Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 20:9-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò fi ṣiṣẹ́, kí ìwọ kí ó ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ,

10. Ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìsinmi Olúwa Ọlọ́run rẹ. Nínú rẹ̀ ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́kiṣẹ́ kan: ìwọ, àti ọmọ rẹ ọkunrìn àti ọmọ rẹ obìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ọkùnrin tàbí ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ obìnrin, tàbí ẹran ọ̀sìn rẹ, àti àlejò rẹ tó wà ní nínú ibodè rẹ.

11. Nítorí ní ọjọ́ mẹ́fà ni Ọlọ́run dá ọ̀run àti ayé, òkun àti gbogbo nǹkan tí ó wà nínú rẹ̀, ṣùgbọ́n ó sinmi ní ọjọ́ keje. Nítorí náà ni Olúwa ṣe bùkún ọjọ́ ìsinmi tí ó sì yà á sí mímọ́.

12. “Bọ̀wọ̀ fún baba àti ìyá rẹ, kí ọjọ́ rẹ bá a le pẹ́ ní orí ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ.

13. “Ìwọ kò gbọdọ̀ pa ènìyàn.

14. “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà.

15. “Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè.

16. “Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké sí ẹnìkejì rẹ.

17. “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojú kòkòrò sí ilé aládùúgbò rẹ. Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojú kòkòrò sí aya aládùúgbò rẹ̀, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ọkùnrin tàbí sí ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin, akọ màlúù rẹ̀ tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ tàbí ohunkóhun tí ó jẹ́ ti aládùúgbò rẹ.”

18. Nígbà tí àwọn ènìyàn náà rí mọ̀nàmọ́ná tí wọ́n sí gbọ́ ohùn ìpè àti èéfín tí ń rú láti orí òkè, tí wọ́n sì gbọ́ sísán àrá, dídún ìpè kíkankíkan; wọ́n dúró ní òkèrè wọ́n sì ń gbọ̀n sìgàsìgà fún ìbẹ̀rù.

19. Wọ́n wí fún Mósè pé, “Ìwọ fúnraàrẹ máa bá wa sọ̀rọ̀, àwa yóò sì gbọ́. Má ṣe jẹ́ kí Ọlọ́run fúnraarẹ̀ kí ó bá wa sọ̀rọ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò kú.”

20. Mósè sì sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ má bẹ̀rù. Ọlọ́run wá láti dán an yín wò, kí ẹ̀rù Ọlọ́run kí ó lè máa wà ní ara yín, kí ẹ̀yin kí ó má ṣe sẹ̀.”

Ka pipe ipin Ékísódù 20