Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 20:21-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Àwọn ènìyàn sì dúró ní òkèèrè nígbà tí Mósè súnmọ́ ibi òkùnkùn biribiri níbi tí Ọlọ́run wà.

22. Olúwa sì sọ fún Mósè pé, “Sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí fún àwọn ará Ísírẹ́lì: ‘Ẹ̀yin ti rí i fúnraayín bí èmi ti bá a yín sọ̀rọ̀ láti ọ̀run wá.

23. Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ sin Ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi: ẹ̀yin kò gbọdọ̀ rọ ọlọ́run fàdákà tàbí ọlọ́run wúrà fún ara yín.

24. “ ‘Pẹpẹ erùpẹ̀ ni kí ìwọ mọ fún mi. Ní orí pẹpẹ yìí ni kí ìwọ ti máa rú ẹbọ sísun rẹ sí mi àti ẹbọ àlàáfíà rẹ, àgùntàn rẹ, ewúrẹ́ àti akọ màlúù rẹ. Ní ibi gbogbo tí mo gbé fi ìrántí orúkọ mi sí, èmi yóò sì máa tọ̀ ọ́ wá, èmi yóò sì máa bùkún ọ níbẹ̀.

Ka pipe ipin Ékísódù 20