Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 20:14-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà.

15. “Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè.

16. “Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké sí ẹnìkejì rẹ.

17. “Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojú kòkòrò sí ilé aládùúgbò rẹ. Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojú kòkòrò sí aya aládùúgbò rẹ̀, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ọkùnrin tàbí sí ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin, akọ màlúù rẹ̀ tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ tàbí ohunkóhun tí ó jẹ́ ti aládùúgbò rẹ.”

18. Nígbà tí àwọn ènìyàn náà rí mọ̀nàmọ́ná tí wọ́n sí gbọ́ ohùn ìpè àti èéfín tí ń rú láti orí òkè, tí wọ́n sì gbọ́ sísán àrá, dídún ìpè kíkankíkan; wọ́n dúró ní òkèrè wọ́n sì ń gbọ̀n sìgàsìgà fún ìbẹ̀rù.

19. Wọ́n wí fún Mósè pé, “Ìwọ fúnraàrẹ máa bá wa sọ̀rọ̀, àwa yóò sì gbọ́. Má ṣe jẹ́ kí Ọlọ́run fúnraarẹ̀ kí ó bá wa sọ̀rọ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò kú.”

20. Mósè sì sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ má bẹ̀rù. Ọlọ́run wá láti dán an yín wò, kí ẹ̀rù Ọlọ́run kí ó lè máa wà ní ara yín, kí ẹ̀yin kí ó má ṣe sẹ̀.”

21. Àwọn ènìyàn sì dúró ní òkèèrè nígbà tí Mósè súnmọ́ ibi òkùnkùn biribiri níbi tí Ọlọ́run wà.

Ka pipe ipin Ékísódù 20