Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 2:9-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ọmọbìnrin Fáráò sì wí fún un pé, “Gba ọmọ yìí kí o sì tọ́jú rẹ̀ fún mi, èmi yóò san owó iṣẹ́ ẹ̀ rẹ fún ọ” Ọmọbìnrin náà sì gbé ọmọ náà lọ, ó sì tọ́jú rẹ̀.

10. Nígbà tí ọmọ náà sì dàgbà, ó mú un tọ ọmọbìnrin Fáráò wá, ó sì di ọmọ rẹ̀. Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Mósè, ó wí pé “Nítorí tí mo fà á jáde nínú omi.”

11. Ní ọjọ́ kan, nígbà tí Mósè ti dàgbà, ó jáde lọ sí ibi ti àwọn ènìyàn rẹ̀ wà, ó ń wò wọ́n lẹ́nu iṣẹ́ líle wọn, O ri ará Éjíbítì tí ń lu ará Ébérù, ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn rẹ̀.

12. Ó wo ìhín, ó wo ọ̀hún, nígbà tí kò rí ẹnìkankan, ni ó bá pa ará Éjíbítì náà, ó sì bò ó mọ́ inú iyanrìn.

13. Ní ọjọ́ kejì, ó jáde lọ, ó rí àwọn ará Hébérù méjì tí wọ́n ń jà. Ó béèrè lọ́wọ́ èyí tí ó jẹ̀bi pé “Èéṣe tí ìwọ fi ń lu Hébérù arákùnrin rẹ?”

14. Ọkùnrin náà sì dáhùn pé “Ta ni ó fi ọ́ jẹ olórí àti onídájọ́ lórí wa? Ṣé o fẹ́ pa mí bí o ṣe pa ará Éjíbítì?” Nígbà náà ni ẹ̀rù ba Mósè, ó rò nínú ara rẹ̀ pé “ó ní láti jẹ́ wí pé ohun tí mo ṣe yìí ti di mímọ̀.”

15. Nígbà ti Fáráò sì gbọ́ nípa èyí, ó wá ọ̀nà láti pa Mósè, ṣùgbọ́n Mósè sá kúrò ní àrọ́wọ́tó o Fáráò, ó lọ sí Mídíánì láti máa gbé, nígbà tí ó dé bẹ̀, ó jókòó ni ẹ̀bá a kànga kan.

16. Ó sì ṣe, àlùfáà Mídíánì kan ni àwọn ọmọbìnrin méje, wọn sì wá láti pọn omi kún ọpọ́n ìmumi fún ẹran ọ̀sìn baba wọn.

17. Àwọn darandaran kán wá, wọ́n sì lé wọn sẹ́yìn, ṣùgbọ́n Mósè dìde láti gbà wọ́n sílẹ̀ àti láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fún ẹran wọn ní omi.

Ka pipe ipin Ékísódù 2