Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 19:7-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Mósè sì tọ àwọn ènìyàn wá, ó sí pe àwọn àgbààgbà láàárin àwọn ènìyàn jọ. Ó sì gbé gbogbo ọ̀rọ̀ ti Olúwa pàṣẹ fún un láti sọ ni iwájú wọn.

8. Gbogbo àwọn ènìyàn náà sì pa ohùn wọn pọ̀ wọ́n sì dáhùn wí pé, “Àwa yóò se ohun gbogbo ti Olúwa wí.” Mósè sì mú ìdáhùn wọn padà tọ Olúwa lọ.

9. Olúwa sọ fún Mósè pé, “Èmi yóò tọ̀ ọ́ wá nínú ìkùùkuu síṣú dudu, kí àwọn ènìyàn lè gbọ́ ohùn mi nígbà ti mo bá ń bá ọ sọ̀rọ̀, kí wọn kí ó lè máa gbà ọ́ gbọ́.” Nígbà náà ni Mósè sọ ohun tí àwọn ènìyàn wí fún Olúwa.

10. Olúwa sì wí fún Mósè pé, “Tọ àwọn ènìyàn lọ kí o sì yà wọ́n sí mímọ́ ni òní àti ni ọ̀la. Jẹ́ kí wọn kí ó fọ aṣọ wọn.

11. Kí wọn kí ó sì múra di ọjọ́ kẹ́ta, nítorí ni ọjọ́ náà ni Olúwa yóò sọ̀kalẹ̀ sí orí òkè Ṣínáì ni ojú gbogbo àwọn ènìyàn.

12. Kí ìwọ kí ó se ààlà fún àwọn ènìyàn, ibi tí wọn lè dé dúró, kí ìwọ kí ó sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ ṣọ́ra! Ẹ má ṣe gun orí òkè lọ, kí ẹ máa tilẹ̀ fi ọwọ́ kan etí ààlà rẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkè náà yóò kú:

13. Ọwọ́kọ́wọ́ kò gbọdọ̀ kàn án, ẹni tí ó fi ọwọ́ kan òkè náà a ó sọ ọ́ ní òkúta tàbí kí a ta a ní ọfà, ìbá à ṣe ènìyàn tàbí ẹranko: Òun kì yóò wà láàyè.’ Nígbà ti ìpè bá dún nìkan ni kí wọn ó gun òkè wá.”

14. Mósè sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn, ó yà wọ́n sí mímọ́, wọ́n sì fọ aṣọ wọn.

Ka pipe ipin Ékísódù 19