Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 19:13-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Ọwọ́kọ́wọ́ kò gbọdọ̀ kàn án, ẹni tí ó fi ọwọ́ kan òkè náà a ó sọ ọ́ ní òkúta tàbí kí a ta a ní ọfà, ìbá à ṣe ènìyàn tàbí ẹranko: Òun kì yóò wà láàyè.’ Nígbà ti ìpè bá dún nìkan ni kí wọn ó gun òkè wá.”

14. Mósè sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn, ó yà wọ́n sí mímọ́, wọ́n sì fọ aṣọ wọn.

15. Ó sì sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ múra sílẹ̀ di ọjọ́ kẹta; Ẹ má ṣe bá aya yín lòpọ̀.”

16. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ kẹ́ta, àrá àti mọ̀nàmọ́ná sì wà pẹ̀lú ìkùùkuu tí ó sú dudu ní orí òkè, ìpè ńlá sì dún kíkan kíkan tó bẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn tí ó wà ni ibùdó wárìrì.

17. Mósè sì kó àwọn ènìyàn tí ó jáde láti ibùdó wá pàdé Ọlọ́run, wọ́n dúró nítòsí òkè.

18. Èéfín sì bo òkè Sínáì nítorí Olúwa sọ̀kalẹ̀ sí orí rẹ̀ nínú iná. Èéfín náà sì ń ru sókè bí èéfín iná ìléru, gbogbo òkè náà sì mì tìtì.

19. Ohùn ìpè sì ń rinlẹ̀ dòdò. Mósè sọ̀rọ̀, Ọlọ́run sì fi àrá dá a lóhùn.

20. Olúwa sọ̀kalẹ̀ sí orí òkè Ṣínáì, o sì pe Mósè wá sí orí òkè náà. Mósè sì gun orí òkè.

21. Olúwa sọ fún Mósè pé, “Sọ̀kalẹ̀, kí ó sì kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn, kí wọn má ṣe fi tipátipá wá ọ̀nà láti wo Olúwa, bí wọn bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ wọn yóò ṣègbé.

22. Kódà àwọn àlùfáà tí ó ń wá ṣíwájú Olúwa gbọdọ̀ ya ara wọn sí mímọ́ bí bẹ́ẹ̀ kọ́. Olúwa yóò kọ lù wọ́n.”

Ka pipe ipin Ékísódù 19