Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 18:9-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Inú Jẹ́tírò dùn láti gbọ́ gbogbo ohun rere ti Olúwa ṣe fún Ísírẹ́lì, ẹni tí ó mú wọ́n jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì.

10. Jẹ́tírò sì wí pé, “Ìyìn ni fún Olúwa, ẹni tí ó gba yín là kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Éjíbítì àti lọ́wọ́ Fáráò, ẹni tí ó sì gbà àwọn ènìyàn là kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Éjíbítì.

11. Mo mọ nísinsìnyìí pé Olúwa tóbi ju gbogbo àwọn òrìṣà lọ; nítorí ti ó gba àwọn ènìyàn rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìgbéraga àti ìkà àwọn ará Éjíbítì.”

12. Jẹ́tírò, àna Mósè, mú ọrẹ sísun àti ẹbọ wá fún Ọlọ́run. Árónì àti gbogbo àgbààgbà Ísírẹ́lì sì wá láti bá àna Mósè jẹun ní iwájú Ọlọ́run.

13. Ní ọjọ́ kejì, Mósè jókòó láti máa ṣe ìdájọ́ fún àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀; àwọn ènìyàn sì dúró ti Mósè fún ìdájọ́ wọn láti òwúrọ̀ títí di ìrọ̀lẹ́.

14. Nígbà tí àna Mósè rí bí àkókò ti èyí ń gba ti pọ̀ tó àti ti àwọn ènìyàn ti ń dúró pẹ́ tó, ó wí pé, “Kí ni èyí tí ìwọ ń se sí àwọn ènìyàn? Èéṣe ti ìwọ nìkan jòkóò gẹ́gẹ́ bí adájọ́, nígbà tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí dúró yí ọ ká láti òwúrọ̀ di ìrọ̀lẹ́?”

15. Mósè dá a lóhùn pé, “Nítorí àwọn ènìyàn ń tọ̀ mí wá láti mọ́ ìfẹ́ Ọlọ́run.

16. Nígbà tí wọ́n bá ní ẹjọ́, wọn a mú un tọ̀ mí wá, èmi a sì ṣe ìdájọ́ láàrin ẹnìkín-ín-ní àti ẹnikejì, èmi a sì máa mú wọn mọ ofin àti ìlànà Ọlọ́run.”

17. Àna Mósè dá a lóhùn pé, “Ohun ti o ń ṣe yìí kò dára.

18. Ìwọ àti àwọn ènìyàn ti ń tọ̀ ọ́ wá yìí yóò dá ara yín ní agara; iṣẹ́ yìí pọ̀ jù fún ọ, ìwọ nìkan kò lè dá a ṣe

19. Nísinsìnyìí, fetísílẹ̀ sí mi, èmi yóò sì gbà ọ́ ni ìmọ̀ràn, Ọlọ́run yóò sì wà pẹ̀lú rẹ. Ìwọ gbọdọ̀ jẹ́ aṣojú àwọn ènìyàn wọ̀nyí níwájú Ọlọ́run, ìwọ yóò sì mú èdè àìyedè wá sí iwájú rẹ̀.

20. Kọ́ wọn ní ofin àti ìlànà Ọlọ́run, fi ọ̀nà igbe ayé ìwà bí Ọlọ́run hàn wọ́n àti iṣẹ́ tí wọn yóò máa ṣe.

21. Sà àwọn tí ó kún ojú òṣùwọ̀n nínú gbogbo àwọn ènìyàn: àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run, ti wọ́n jẹ́ olóòótọ́, tí wọ́n kórìíra ìrẹ́jẹ: yàn wọ́n se olórí: lórí ẹgbẹ̀rún-ẹgbẹ̀rún, ọgọ́rùn-ún-ọgọ́rùn-un, àádọ́ta-àádọ́ta àti mẹ́wàá-mẹ́wàá.

22. Jẹ́ kí wọn ó máa ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn ni gbogbo ìgbà, ṣùgbọ́n jẹ́ kí wọn mú ẹjọ́ tí ó bá nira fún wọn láti dá tọ̀ ọ́ wá; kí wọn kí ó máa dá ẹjọ́ kéékèèkéé. Èyí ni yóò mú iṣẹ́ rẹ rọrùn, wọn yóò sì máa ràn ọ́ lọ́wọ́ lórí ìdájọ́ ṣíṣe.

23. Bí ìwọ bá ṣe èyí, bí Ọlọ́run bá sì fi àṣẹ sí i fún ọ bẹ́ẹ̀, àárẹ̀ kò sì ní tètè mu ọ, àwọn ènìyàn wọ̀nyí yóò sì padà lọ ilé wọn ni ìtẹ́lọ́rùn.”

Ka pipe ipin Ékísódù 18