Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 16:21-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Ní òwúrọ̀, ni ojoojúmọ́ ni ẹnìkọ̀ọ̀kan ń lọ kó ìwọ̀nba ti ó tó fún un láti jẹ, bí òòrùn bá sì mú, a sì yọ́.

22. Ní ọjọ́ kẹfà, wọ́n kó ìlọ́po méjì èyí ti wọn ń kó tẹ́lẹ̀: òṣùnwọn ómérì méjì fún ẹnìkọ̀ọ̀kan; àwọn olórí ìjọ ènìyàn sì wá, wọ́n sì sọ èyí fún Mósè.

23. Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ: ‘Ọ̀la jẹ́ ọjọ́ ìsinmi, ìsinmi mímọ́ fún Olúwa. Ẹ yan èyí ti ẹ̀yin ní yan, kí ẹ sì bọ èyí ti ẹ̀yin ní bọ̀. Ẹ tọ́jú èyí ti ó kù sílẹ̀, kí ẹ pa á mọ́ di òwúrọ̀.’ ”

24. Wọ́n sì tọ́jú rẹ̀ di òwúrọ̀ bí Mósè ti pàṣẹ; kò sì rùn bẹ́ẹ̀ ni kò sì ní ìdin.

25. Mósè sì wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ ẹ́ ní òní nítorí òní jẹ́ ọjọ́ ìsinmi Olúwa. Ẹ̀yin kò ni rí i ni orí ilẹ̀ ní ọjọ́ òní.

26. Ní ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi kó o, ṣùgbọ́n ni ọjọ́ keje ọjọ́ ìsinmi, kò ní sí i fún un yín ni ọjọ́ náà.”

27. Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ àwọn ènìyàn kan jáde lọ ní ọjọ́ keje láti kó o, ṣùgbọ́n wọn kò ri nǹkan kan kó.

28. Olúwa sì sọ fún Mósè pé, “Yóò ti pẹ́ tó ti ẹ ó kọ̀ láti pa àṣẹ mi àti ìlànà mi mọ́?

29. Wò ó? Olúwa ti fún un yín ni ọjọ́ ìsinmi, nítorí náà, ni ọjọ́ kẹfà, ó fún un yín ni ounjẹ ọjọ́ méjì; kí ẹnìkọọkan dúró ni ibi tí ó gbé wà; kí ẹ má ṣe kúrò ni ibi tí ẹ wà ni ọjọ́ keje.”

30. Nítorí náà, àwọn ènìyàn sinmi ní ọjọ́ keje.

31. Àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì sì pe oúnjẹ náà ní Mánà. Ó funfun bí irúgbìn kóríáńdà, ó sì dùn bí burẹ́dì fẹlẹfẹlẹ ti a fi oyin ṣe.

Ka pipe ipin Ékísódù 16