Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 16:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú ọ̀nà wọn pọ̀n kúrò ni Élímù, wọ́n dé sí ijù Sínì tí ó wà láàrin Élímù àti Ṣínáì, ni ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù kejì tí wọ́n jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì.

2. Ní ijù náà ni ìjọ àwọn ènìyàn ti kùn sí Mósè àti Árónì.

3. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wí fún wọn pé, “Àwa ìbá ti ọwọ́ Olúwa kú ni Éjíbítì! Níbi tí àwa ti jókòó ti ìkòkò ẹran ti a sì ń jẹ ohun gbogbo tí a fẹ́ ni àjẹyó, ṣùgbọ́n ẹ̀yin mú wa wá sí inú ijù yìí láti fi ebi pa wá tí a ó fi kú.”

4. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, “Èmi yóò rọ òjò oúnjẹ láti ọ̀run wá fún yín. Àwọn ènìyàn yóò sì máa jáde lọ ni ọjọ́ kọ̀ọ̀kan láti kó ìwọ̀nba oúnjẹ ti ó tó fún oúnjẹ òòjọ́ wọn. Ní ọ̀nà yìí ni, èmi yóò fi dán wọn wò láti mọ bóyá wọn yóò máa tẹ̀lé ìlànà mi.

5. Ní ọjọ́ kẹfà, ki wọn kó ìlọ́po méjì èyí ti wọn ń ko ni ojoojúmọ́ tẹ́lẹ̀.”

6. Mósè àti Árónì sọ fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, “Ní ìrọ̀lẹ́, ẹ̀yin yóò mọ̀ pé Olúwa ni ó mú un yín jáde láti Éjíbítì wá.

7. Ní òwúrọ̀, ẹ̀yin yóò ri ògo Olúwa, nítorí òun ti gbọ́ kíkùn tí ẹ kùn sí i. Ta ni àwa ti ẹ̀yin yóò máa kùn sí wa?”

8. Mósè tún wí pé, “Ẹ̀yin yóò mọ pé Olúwa ni, nígbà ti ó bá fún un yín ni ẹran ni ìrọ̀lẹ̀ àti gbogbo oúnjẹ ti ẹ̀yin ń fẹ́ ni òwúrọ̀, nítorí kíkún ti ẹ̀yin ń kùn sí i. Ta ni àwa? Ẹ̀yin kò kùn sí àwa, Olúwa ni ẹ̀yin kùn sí i.”

9. Nígbà náà ni Mósè sọ fún Árónì pe, “Sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pe, ‘Ẹ wá sí iwájú Olúwa, nítorí òun ti gbọ́ kíkùn yín.’ ”

10. Ó sì ṣe bí Árónì ti ń bá gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀, wọn si bojúwo ìhà ijù, sì kíyèsi ògo Olúwa si farahàn ni àwọ̀-sánmọ̀.

Ka pipe ipin Ékísódù 16