Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 15:4-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Kẹ̀kẹ́-ogun Fáráò àti ogun rẹ̀ni ó mú wọ inú òkun.Àwọn ọmọ ogun Fáráò tó jáfáfá jùlọni ó rì sínú òkun pupa.

5. Ibú omi bò wọ́n mọ́lẹ̀;Wọ́n sì rì sí ìsàlẹ̀ omi òkun bí òkúta.

6. “Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, Olúwa,pọ̀ ní agbára.Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, Olúwa,fọ́ àwọn ọ̀ta túútúú.

7. Nínú agbára ńlá rẹ ti ó tóbiìwọ bi àwọn ti ó dìde sí ọ ṣubú.Ìwọ rán ìbínú gbígbóná rẹ;Tí ó run wọ́n bí ìgémọ́lẹ̀ ìdí koríko

8. Pẹ̀lú èémí imú rẹ ni omi fi ńwọ́jọ pọ̀Ìsàn omi dìde dúró bí odi;Ibú omi sì dìpọ̀ láàrin òkun.

9. “Ọ̀ta ń gbéraga, ó ń wí pé:‘Èmi ó lépa wọn, èmi ó bá wọn.Èmi ó pín ìkógun;Èmi ó tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ mi lọ́run lára wọn.Èmi yóò fa idà mi yọ, ọwọ́ mi yóò pa wọ́n run.’

10. Ìwọ fẹ́ èèmí rẹòkun ru bò wọ́n mọ́lẹ̀wọ́n rì bí òjéni àárin omi ńlá.

11. “Ta ni nínú àwọn òrìṣà tó dàbí rẹ, Olúwa?Ta ló dàbí rẹ:ní títóbi,ní mímọ́ Ẹlẹ́rù ni yìnTí ń se ohun ìyanu?

12. Ìwọ na apá ọ̀tún rẹIlẹ̀ si gbé wọn mì.

13. “Nínú ìfẹ́ rẹ ti kì í ṣákìíìwọ se amọ̀nàÀwọn ènìyàn náà tí ìwọ ti ràpadàNínú agbára rẹ ìwọ yóò tọ́ wọn lọsí ibi ìjókòó rẹ mímọ́.

14. Orílẹ̀-èdè yóò gbọ́ wọn yóò wárìrìÌkáàánú yóò mi àwọn ènìyàn palẹ́sítínì.

15. Ìbẹ̀rù yóò mú àwọn ìjòyè Édómù,Àwọn olórí Móábù yóò wárìrìÀwọn ènìyàn Kénánì yóò sì yọ̀ danu;

16. Ìbẹ̀rù-bojo yóò subú lù wọ́n nítorínína títóbi apá rẹ̀wọn yóò dúró jẹ́ ẹ́ láì mira bí i òkútaTítí àwọn ènìyàn rẹ yóò fi ré kọjá, Olúwa,Títí tí àwọn ènìyàn tí o ti rà yóò fi ré kọjá.

17. Ìwọ yóò mú wọn wá láti gbìn wọ́nni ori òkè ti ìwọ jogún;Ní ibi ti ìwọ ṣe fún ara rẹ, Olúwa.Láti máa gbé ibi mímọ́ ti ìwọ fi ọwọ́ rẹ gbékalẹ̀, Olúwa.

18. Olúwa yóò jọbaláé àti láéláé.”

19. Nígbà ti ẹsin Fáráò, kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́sin rẹ̀ wọ inú òkun, Olúwa mú kí omi òkun padà bò wọ́n mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rìn lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ la òkun kọjá.

20. Míríámù wòlíì obìnrin, arábìnrin Árónì, mú ohun èlò orin ni ọwọ́ rẹ̀, àwọn obìnrin ti ó tẹ̀lé pẹ̀lú mú ohun èlò orin wọ́n sì ń jó.

21. Míríámà kọrin sí wọn báyìí pé:“Ẹ kọrin sí OlúwaNítorí òun ni ológo jùlọẸṣin àti ẹni tí ó gùn únNi òun bi subú sínú òkun.”

Ka pipe ipin Ékísódù 15