Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 14:23-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

23. Àwọn ará Éjíbítì sì ń lépa wọn, gbogbo ẹsin Fáráò, kẹ́kẹ́-ogun àti àwọn ẹlẹ́sin rẹ̀ wọ́ tọ̀ wọ́n lọ sínú òkun.

24. Ní ìsọ́ òwúrọ̀ (láàárin ago mẹ́ta sí mẹ́ta òwúrọ̀) Olúwa bojúwo ogun àwọn ará Éjíbítì láàrin òpó iná àti ìkùùkuu, ó sì kó ìpayà bá àwọn ọmọ ogun Éjíbítì.

25. Ó sì yọ àgbá ẹsẹ̀ kẹ̀kẹ́ ogun wọn kí ó bá à le ṣòro fún wọn láti fi kẹ̀kẹ́-ogun náà rìn. Àwọn ará Éjíbítì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a sá àṣálà kúrò ní iwájú àwọn ará Ísírẹ́lì nítorí Olúwa ń bá wa jà nítorí wọn.”.

26. Olúwa sì wí fún Mósè pé, “Na ọwọ́ rẹ sí orí òkun kí omi òkun lè ya padà sórí àwọn ará Éjíbítì, kẹ̀kẹ́ ogun wọn àti sórí ẹlẹ́sin wọn.”

27. Mósè sì na ọwọ́ rẹ̀ sí orí òkun, òkun sì padà bọ́ sí ipò rẹ̀ nígbà ti ìlẹ̀ mọ́. Àwọn ará Éjíbítì ń sá fún omi òkun, Olúwa sì gbá wọn sínú òkun.

28. Omi òkun sì ya padà, ó sì bo kẹ̀kẹ́-ogun àti àwọn ẹlẹ́sin: àní, gbogbo ọmọ ogun Fáráò ti wọn wọ inú òkun tọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ kò sí ọ̀kan nínú wọn ti o yè.

29. Ṣùgbọ́n àwọn ará Ísírẹ́lì la òkun kọjá lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ pẹ̀lú ògiri omi ni ọ̀tún àti òsì wọn.

30. Ni ọjọ́ yìí ni Olúwa gba Ísírẹ́lì là kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Éjíbítì; Ísírẹ́lì sì rí òkú àwọn ará Éjíbítì ni etí òkun.

31. Nígbà ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí iṣẹ́ ìyanu ńlá ti Olúwa se fún wọn lára àwọn ará Éjíbítì, àwọn ènìyàn bẹ̀rù Olúwa, wọ́n sì gba Olúwa àti Mósè ìráńṣẹ́ rẹ gbọ́.

Ka pipe ipin Ékísódù 14