Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 12:5-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ẹran tí ìwọ yóò mú gbọdọ̀ jẹ́ akọ ọlọ́dùn kan tí kò lábùkù, ìwọ lè mú lára àgbò tàbí ewúrẹ́.

6. Ṣe ìtọ́jú wọn títí di ọjọ́ kẹrìnlá oṣù yìí nígbà tí gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì yóò pa ẹran náà ní àfẹ̀mójúmọ́.

7. Wọn yóò mú lára ẹ̀jẹ̀ ẹran náà, wọn yóò fi kan ẹ̀gbẹ́ méjèèjì àti òkè ẹnu ọ̀nà àbáwọlé níbi tí wọ́n bá ti jẹ ẹran ọ̀dọ́ àgùntàn náà.

8. Ní òru ọjọ́ kan náà, wọn yóò jẹ ẹran tí a ti fi iná sun, pẹ̀lú ewe ewúro àti búrẹ̀dì aláìwú.

9. Ẹ má ṣe jẹ ẹran náà ni tútù tàbí ní bíbọ̀ nínú omi, ṣùgbọ́n kí ẹ fi iná sun orí, ẹsẹ̀ àti àwọn nǹkan inú ẹran náà.

10. Ẹ má ṣe fi èyíkéyìí sílẹ̀ di òwúrọ̀ ọjọ̀ kejì, bí ó bá sẹ́ kú di òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, kí ẹ jó o níná.

11. Báyìí ni ẹ̀yìn yóò ṣe jẹ tí ẹ̀yin ti àmùrè ní ẹ̀gbẹ́ yín, sáńdà yín ní ẹsẹ̀ yín àti ọ̀pá yín ni ọwọ́ yín. Ẹ yára jẹ ẹ́, oúnjẹ àjọ ìrékọjá Olúwa ni.

12. “Ní òru ọjọ́ yìí kan náà ni èmi yóò la gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì kọjá, èmi yóò sì pa gbogbo àkọ́bí àtènìyàn, àtẹranko, èmi yóò mú ìdájọ́ wà sí orí àwọn òrìṣà ilẹ̀ Éjíbítì. Èmi ni Olúwa.”

13. Ẹ̀jẹ̀ ni yóò jẹ́ àmì fún un yín ní àwọn ilé tí ẹ̀yin wà, nígbà tí èmi bá rí ẹ̀jẹ̀ náà, èmi yóò ré e yín kọjá. Ìyọnu kì yóò kàn yín nígbà tí èmi bá kọlu Éjíbítì láti pa wọ́n run.

14. “Èyí ni ọjọ́ tí ẹ̀yin yóò máa ṣe ìrántí láàrin àwọn ìran tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn ni ẹ̀yin yóò ti máa ṣe àjọ ọdún rẹ fún Olúwa; ìlànà tí yóò wà títí ayé.

15. Fún ọjọ́ méje ni ẹ̀yin yóò fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, ẹ ó gbé ìwúkàrà kúrò ni ilé yín, nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ ohunkóhun tí ó ni ìwúkàrà nínú láti ọjọ́ kìn-ín-ní di ọjọ́ keje ni kí a yọ kúrò ni Ísírẹ́lì.

Ka pipe ipin Ékísódù 12