Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 10:5-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Wọn yóò bo gbogbo ilẹ̀. Wọn yóò ba ohun gbogbo tí ó kù fún ọ lẹ́yìn òjò yìnyín jẹ́, tí ó fi dórí gbogbo igi tí ó ń dàgbà ni ilẹ̀ rẹ.

6. Wọn yóò kún gbogbo ilé rẹ àti ilé àwọn ìjòyè rẹ àti ilé gbogbo àwọn ará Éjíbítì. Ohun ti baba rẹ tàbí baba baba rẹ kò tí ì rí láti ìgbà tí wọ́n ti wà ní ilẹ̀ náà títí di àkókò yìí.’ ” Nígbà náà ni Mósè pẹ̀yìndà kúrò níwájú Fáráò.

7. Àwọn ìjòyè Fáráò sọ fún “Yóò ti pẹ to tí ọkùnrin yìí yóò máa mú ìyọnu bá wa? Jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí lọ, kí wọn kí ó le sìn Olúwa Ọlọ́run wọn. Ṣe ìwọ kò ṣe àkíyèsí ṣíbẹ̀ pé, ilẹ̀ Éjíbítì ti parun tán?”

8. Nígbà náà ni a mú Árónì àti Mósè padà wá sí iwájú Fáráò ó sì wí fún wọn pé “Ẹ lọ sìn Olúwa Ọlọ́run yín. Ṣùgbọ́n àwọn ta ni nínú yín ni yóò ha lọ.”

9. Mósè dáhùn ó wí pé, “A ó lọ pẹ̀lú àwọn ọmọdé àti àgbà wa, pẹ̀lú àwọn ọmọ wa ọkùnrin àti ọmọ wa obìnrin pẹ̀lú agbo àgùntàn wa àti agbo màlúù wa nítorí pé a gbọdọ̀ ṣe ajọ fún Olúwa.”

10. Fáráò sì wí pé, “Mo fi Olúwa búra pé èmi kí yóò jẹ́ kí ẹ lọ, pẹ̀lú àwọn obìnrin yín àti àwọn ọmọ wẹ́wẹ́, dájúdájú èrò ibi ní ń bẹ nínú yín.

11. Rárá! Ọkùnrin yín nìkan ni kí ó lọ, láti lọ sin Olúwa, ní wọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé èyí ni ẹ̀yín ń béèrè fún.” Wọ́n sì lé Mósè àti Árónì kúrò ní iwájú Fáráò.

12. Ní ìgbà náà ni Ọlọ́run sọ fún Mósè, “Gbé ọwọ́ rẹ sókè lórí Éjíbítì kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ eṣú bo gbogbo ilẹ̀, kí ó sì ba gbogbo ohun ọ̀gbìn tí ó wà ni inú oko wọn jẹ́, àní gbogbo ohun tí òjò yìnyín kò bájẹ́ tan.”

13. Nígbà náà ni Mósè na ọ̀pá ọwọ́ rẹ̀ sórí ilẹ̀ Éjíbítì, Olúwa sì mú kí afẹ́fẹ́ láti ìlà oòrùn fẹ́ kọjá lórí ilẹ̀ náà ni gbogbo ọ̀sán àti ni gbogbo òru ni ọjọ́ náà. Ní òwúrọ̀ afẹ́fẹ́ náà ti gbá ọ̀pọ̀lọpọ̀ Esú wá;

14. Wọ́n sì bo gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì, wọ́n wà ní ibi gbogbo ní orí ilẹ̀ ní àìmoye, ṣáájú àkókò yìí kò sí irú ìyọnu Esú bẹ́ẹ̀, rí kò sì ní sí irú rẹ mọ́ lẹ́yìn èyí.

Ka pipe ipin Ékísódù 10