Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 10:21-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, “Gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ojú ọ̀run kí okùnkùn báà le bo gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì; àní òkùnkùn biribiri.”

22. Nígbà náà ni Mósè gbé ọwọ́ rẹ sókè sí ojú ọ̀run, òkùnkùn biribiri sì bo gbogbo ilẹ̀ Éjíbítì fún ọjọ́ mẹ́ta. Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ìmọ́lẹ̀ ní ibi tí wọn ń gbé.

23. Kò sí ẹni tí ó le è ríran rí ẹlòmíràn tàbí kí ó kúrò ní ibi tí ó wà fún ọjọ̀ mẹ́ta. Ṣíbẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ̀lì ni ìmọ́lẹ̀ ni gbogbo ibi tí wọ́n ń gbé.

24. Fáráò sì ránṣẹ́ pe Mósè ó sì wí fún un pé, “Lọ sìn Olúwa, kódà àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé lè lọ pẹ̀lú yín, ṣùgbọ́n kí ìwọ kí ó fi agbo àgùntàn àti agbo màlúù yín sílẹ̀.”

25. Ṣùgbọ́n Mósè sọ pé, “Ìwọ gbọdọ̀ fún wa láàyè láti rúbọ àti ọrẹ ẹbọ sísun ní iwájú Olúwa Ọlọ́run wa.

26. Àwọn ohun ọ̀sìn wa gbọdọ̀ lọ pẹ̀lú wa, a kì yóò fi pátákò ẹṣẹ̀ ẹran sílẹ̀. A ní láti lò lára wọn fún sínsìn Olúwa Ọlọ́run wa, ìgbà tí a bá sì dé ibẹ̀ ni a ó to mọ̀ ohun ti a ó lò láti fi sìn Olúwa.”

27. Ṣùgbọ́n Olúwa ṣé ọkàn Fáráò le, kò sì ṣetan láti jẹ́ kí wọn lọ.

28. Fáráò sọ fún Mósè pé, “Kúrò ní iwájú mi! Rí i dájú pé o kò wá sí iwájú mi mọ́! Ọjọ́ tí ìwọ bá rí ojú mi ni ìwọ yóò kú.”

29. Mósè sì dáhùn pé, gẹ́gẹ́ bí ìwọ ti wí, “Èmi kí yóò wá sí iwájú rẹ mọ́.”

Ka pipe ipin Ékísódù 10