Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 5:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Mósè sì pe gbogbo Ísírẹ́lì jọ, ó sì wí pé: Gbọ́ ìwọ Ísírẹ́lì, gbọ́ ìlànà àti òfin tí mo mú wá sí etíìgbọ ọ yín lónìí. Ẹ kọ wọ́n, kí ẹ sì ri dájú pé ẹ̀ ń ṣe wọ́n.

2. Olúwa Ọlọ́run wa bá wa dá májẹ̀mú ní Hórébù.

3. Kì í ṣe àwọn baba wa ni Olúwa bá dá májẹ̀mú yìí bí kò ṣe àwa, àní pẹ̀lú gbogbo àwa tí a wà láàyè níbí lónìí.

4. Olúwa bá a yín sọ̀rọ̀ lójúkojú láàrin iná lórí òkè.

5. (Ní ìgbà yìí, mo wà láàrin ẹ̀yin pẹ̀lú Ọlọ́run láti sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún un yín torí pé ẹ̀rù Ọlọ́run ń bà yín, ẹ kò sì lè kọjá lọ sórí òkè) Ó sì wí pé:

6. “Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti Íjíbitì láti oko ẹrú wá.

7. “Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ní Ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú ù mi.

8. “Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ ṣe ère fún ara yín ní ìrí ohunkóhun lọ́run tàbí ní ilẹ̀ ní ìṣàlẹ̀ níhìn-ín tàbí nínú omi ní ìṣàlẹ̀.

9. Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ láti sìn wọ́n. Torí pé èmi Olúwa Ọlọ́run yín Ọlọ́run owú ni mí, tí í fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ baba jẹ ọmọ títí dé ìran kẹ́ta àti ẹ̀kẹ́rin ní ti àwọn tí ó kórìíra mi.

10. Ṣùgbọ́n mo ń fí ìfẹ́ han ẹgbẹẹgbẹ̀rùn-ún ìran àwọn tí ó fẹ́ràn mi, tí ó sì ń pa òfin mi mọ́.

11. “Ẹ má ṣe ṣi orúkọ Olúwa Ọlọ́run yín lò, torí pé ẹnikẹ́ni tí o bá ṣi orúkọ rẹ̀ lò kì yóò lọ láìjẹ̀bi.

12. “Ẹ kíyèsí ọjọ́ ìsinmi láti pa á mọ́ bí Olúwa Ọlọ́run yín ti pàṣẹ fún un yín.

Ka pipe ipin Deutarónómì 5