Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 32:3-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Èmi yóò kókìkí orúkọ Olúwa,Áà, ẹ yìn títóbi Ọlọ́run wa!

4. Òun ni àpáta, iṣẹ́ ẹ rẹ̀ jẹ́ pípé,gbogbo ọ̀nà an rẹ̀ jẹ́ òdodo.Ọlọ́run olótìítọ́ tí kò ṣe àsìṣe kan,Ó dúró ṣinṣin, òdodo àti òtítọ́ ni òun.

5. Wọ́n ti ṣe iṣẹ́ ìbàjẹ́ sọ́dọ̀ ọ rẹ̀;fún ìtìjú u wọn, wọn kì í ṣe ọmọ rẹ̀ mọ́,ṣùgbọ́n ìran tí ó yí sí apákan tí ó sì doríkodò.

6. Ṣé báyìí ni ẹ̀yin yóò ṣe san an fún Olúwa,Áà ẹ̀yin aṣiwèrè àti aláìgbọ́n ènìyàn?Ǹjẹ́ òun kọ́ ni baba yín, Ẹlẹ́dàá yín,tí ó dá a yín tí ó sì mọ yín?

7. Rántí ìgbà láéláé;wádìí àwọn ìran tí ó ti kọjá.Béèrè lọ́wọ́ baba à rẹ yóò sì sọ fún ọ,àwọn àgbà rẹ, wọn yóò sì ṣàlàyé fún ọ.

8. Nígbà tí atóbijù fi ogún àwọn orílẹ̀ èdè fún wọn,nígbà tí ó pín onírúurú ènìyàn,ó sì gbé ààlà kalẹ̀ fún àwọn ènìyàngẹ́gẹ́ bí iye ọmọkùnrin Ísírẹ́lì.

9. Nítorí ìpín Olúwa ni àwọn ènìyàn an rẹ̀,Jákọ́bù ni ìpín ìní i rẹ̀.

10. Ní ihà ni ó ti rí i,ní ihà níbi tí ẹranko kò sí.Ó yíká, ó sì tọ́jú u rẹ̀,ó pa á mọ́ bí ẹyin ojú u rẹ̀.

11. Bí idì ti íru ìtẹ́ rẹ̀ ti ó sì ńrábàbà sórí ọmọ rẹ̀,tí ó na ìyẹ́ apá rẹ̀ láti gbé wọn ki ó sìgbé wọn sórí ìyẹ́ apá rẹ̀.

Ka pipe ipin Deutarónómì 32