Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 28:32-42 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

32. Àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ yóò di mímú fún àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn, ìwọ yóò sì fi ojú ù rẹ sọ́nà dúró dè wọ́n láti ọjọ́ dé ọjọ́, ìwọ yóò sì jẹ́ aláìlágbára láti gbé ọwọ́.

33. Èṣo ilẹ̀ rẹ àti gbogbo iṣẹ́ làálàá rẹ ni orílẹ̀-èdè mìíràn tí ìwọ kò mọ̀ yóò sì jẹ, ìwọ yóò jẹ́ kìkì ẹni ìnilára àti ẹni ìtẹ̀mọ́lẹ̀

34. Ìran tí ojú ù rẹ yóò rí, yóò sọ ọ́ di òmùgọ̀.

35. Olúwa yóò lu eékún àti ẹṣẹ̀ rẹ pẹ̀lú oówo dídùn tí kò le san tán láti àtẹ́lẹṣẹ̀ méjèèjì rẹ lọ sí òkè orí rẹ.

36. Olúwa yóò lé ọ àti ọba tí ó yàn lóríì rẹ lọ sí orílẹ̀ èdè tí ìwọ kò mọ̀ tàbi ti àwọn baba rẹ kò mọ̀. Ibẹ̀ ni ìwọ̀ yóò sì sin ọlọ́run mìíràn, ọlọ́run igi àti òkúta.

37. Ìwọ yóò padà wá di ohun ìbẹ̀rù àti ohun ẹ̀gàn àti ẹlẹ́yà sí gbogbo orílẹ̀ èdè tí Olúwa yóò lé ọ lọ.

38. Ìwọ yóò gbin irúgbìn púpọ̀ ṣùgbọ́n ìwọ yóò kórè kékeré, nítorí eṣú yóò jẹ̀ ẹ́ run.

39. Ìwọ yóò gbin ọgbà àjàrà púpọ́ ìwọ yóò sì ro wọ́n ṣùgbọ́n kò ní mú wáìnì náà tàbí kó àwọn èṣo jọ, nítorí kòkòrò yóò jẹ wọ́n run.

40. Ìwọ yóò ní igi ólífì jákèjádò ilẹ̀ rẹ ṣùgbọ́n ìwọ kò ní lo òróró náà, nítorí ólífì náà yóò rẹ̀ dànù.

41. Ìwọ yóò ní àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ṣùgbọ́n ìwọ kò ní pa wọ́n mọ́, nítorí wọn yóò lọ sí ìgbèkùn.

42. Ọ̀wọ́ eṣú yóò gba gbogbo àwọn igi rẹ àti àwọn èso ilẹ̀ rẹ.

Ka pipe ipin Deutarónómì 28