Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 28:21-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Olúwa yóò fi àjàkálẹ̀-àrùn bá ọ jà títí tí yóò fi pa ọ́ run kúrò ní ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní.

22. Olúwa yóò kọlù ọ́ pẹ̀lú àrùn ìgbẹ́, pẹ̀lú ibà àti àìsàn wíwú, pẹ̀lú ìján ńlá àti idà, pẹ̀lú ìrẹ̀dànù àti imúwòdù tí yóò yọ ọ́ lẹ́nu títí ìwọ yóò fi parun.

23. Ojú ọ̀run tí ó wà lórí rẹ yóò jẹ́ idẹ, ilẹ̀ tí ń bẹ níṣàlẹ̀ rẹ yóò sì jẹ́ irin.

24. Olúwa yóò yí òjò ilẹ̀ rẹ sí eekuru ẹ̀tù ìbọn yóò sì wá sílẹ̀ láti ojú ọ̀run títí tí yóò fi pa ọ́ run.

25. Olúwa yóò fi ọ́ gégùn ún láti ṣubú níwájú àwọn ọ̀ta rẹ. Ìwọ yóò tọ̀ wọ́n wá ní ọ̀nà kan ṣùgbọ́n ìwọ yóò ṣá fún wọn ní ọ̀nà méje, ìwọ yóò sì padà di ohun ìbẹ̀rù fún gbogbo ìjọba lórí ayé.

26. Òkú rẹ yóò jẹ́ oúnjẹ fún gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run àti fún ẹranko ayé, àti pé kò ní sí ẹnikẹ́ni tí yóò lé wọn kúrò.

27. Olúwa yóò bá ọ jà pẹ̀lú oówo, Éjíbítì àti pẹ̀lú kókó, ojú egbò kíkẹ̀ àti ìhúnra.

28. Olúwa yóò bá ọ jà pẹ̀lú ìsínwín, ojú fífọ́ àti rúdurùdu àyà.

29. Ní ọ̀sán gangan ìwọ yóò fi ọwọ́ talẹ̀ kiri bí ọkùnrin afọ́jú nínú òkùnkùn ìwọ kì yóò ṣe àṣeyọrí nínú ohun gbogbo tí o bá ń ṣe, ojoojúmọ́ ni wọn yóò máa ni ọ́ lára àti jà ọ́ ní olè, tí kò sì ní í sí ẹnìkan láti gbà ọ́.

30. Ìwọ yóò gba ògo láti fẹ obìnrin kan ṣùgbọ́n ẹlòmíràn yóò gbà á yóò sì tẹ́ ẹ́ ní ògo. Ìwọ yóò kọ́ ilé, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò gbé ibẹ̀. Ìwọ yóò gbin ọgbà àjàrà, ṣùgbọ́n ìwọ kò tilẹ̀ ní gbádùn èṣo rẹ.

31. Màlúù rẹ yóò di pípa níwájú ù rẹ, ṣùgbọ́n ìwọ kì yóò jẹ ìkankan nínú rẹ̀. Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ yóò sì di mímú pẹ̀lú agbára kúrò lọ́dọ̀ rẹ, a kì yóò sì da padà. Àgùntàn rẹ yóò di mímú fún àwọn ọ̀ta rẹ, ẹnìkankan kò sì ní gbà á.

32. Àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin rẹ yóò di mímú fún àwọn orílẹ̀ èdè mìíràn, ìwọ yóò sì fi ojú ù rẹ sọ́nà dúró dè wọ́n láti ọjọ́ dé ọjọ́, ìwọ yóò sì jẹ́ aláìlágbára láti gbé ọwọ́.

33. Èṣo ilẹ̀ rẹ àti gbogbo iṣẹ́ làálàá rẹ ni orílẹ̀-èdè mìíràn tí ìwọ kò mọ̀ yóò sì jẹ, ìwọ yóò jẹ́ kìkì ẹni ìnilára àti ẹni ìtẹ̀mọ́lẹ̀

34. Ìran tí ojú ù rẹ yóò rí, yóò sọ ọ́ di òmùgọ̀.

Ka pipe ipin Deutarónómì 28