Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 23:8-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ìran kẹta àwọn ọmọ tí a bí fún wọn lè wọ ìpéjọ Olúwa.

9. Nígbà tí o bá dó ti àwọn ọ̀ta rẹ, pa gbogbo ohun àìmọ́ kúrò.

10. Bí ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin rẹ bá jẹ́ aláìmọ́ nítorí ìtújáde tí ó ní, o ní láti jáde kúrò nínú àgọ́, kí o má ṣe wọ inú àgọ́.

11. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá di ìrọ̀lẹ́ o ní láti wẹ ara rẹ, àti ní àṣálẹ́ kí o padà sínú àgọ́.

12. Sàmì sí ibìkan lóde àgọ́, níbi tí o lè máa lọ láti dẹ ara rẹ lára.

13. Ìwọ yóò mú igi pẹ̀lú ohun ìjà rẹ àti nígbà tí o bá dẹ ara rẹ lára tán, gbẹ́ kòtò kí o sì bo ìgbẹ́ rẹ.

14. Nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń rìn láàrin àgọ́ láti dáàbò bò ọ́ àti láti fi àwọn ọ̀taà rẹ lé ọ lọ́wọ́. Àgọ́ ọ rẹ ní láti jẹ́ mímọ́, nítorí kí ó má ba à rí ohun àìtọ́ láàrin yín kí ó sì yípadà kúrò lọ́dọ̀ ọ yín.

15. Bí ẹrú kan bá ti gba ààbò lọ́dọ̀ rẹ, má ṣe fi lé ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́.

16. Jẹ́ kí ó máa gbé láàrin rẹ níbikíbi tí ó bá fẹ́ àti èyíkéyí ìlú tí ó bá mú. Má se ni í lára.

17. Kí ọkùnrin tàbí obìnrin Ísírẹ́lì má ṣe padà di alágbérè ojúbọ òrìṣà.

18. O kò gbọdọ̀ mú owó iṣẹ́ panṣágà obìnrin tàbí ọkùnrin wá sí ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ láti fi san ẹ̀jẹ́ kankan; nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ korìíra àwọn méjèèjì.

19. Má ṣe ka èlé sí arákùnrin rẹ lọ́rùn, bóyá lórí owó tàbí oúnjẹ tàbí ohunkóhun mìíràn tí ó lè mú èlé wá.

20. O lè ka èlé sí àlejò lọ́rùn, ṣùgbọ́n kì í ṣe arákùnrin ọmọ Ísírẹ́lì, nítorí kí Olúwa Ọlọ́run rẹ lè bùkún ọ nínú ohun gbogbo tí o bá dáwọ́ lé ní ilẹ̀ tí ò ń wọ̀ lọ láti ní.

Ka pipe ipin Deutarónómì 23