Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 23:5-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀, Olúwa Ọlọ́run rẹ kò ní fetí sí Bálámù ṣùgbọ́n ó yí ègún sí ìbùkún fún ọ, nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ fẹ́ràn rẹ.

6. Má ṣe wá ìpinnu ìbádọ́rẹ́ pẹ̀lú u wọn níwọ̀n ìgbà tí o sì wà láàyè.

7. Má ṣe kórìíra ará Édómù kan nítorí arákùnrin rẹ ni. Má se kórìíra ará Éjíbítì, nítorí o gbé gẹ́gẹ́ bí àléjò ní ilẹ̀ rẹ̀.

8. Ìran kẹta àwọn ọmọ tí a bí fún wọn lè wọ ìpéjọ Olúwa.

9. Nígbà tí o bá dó ti àwọn ọ̀ta rẹ, pa gbogbo ohun àìmọ́ kúrò.

10. Bí ọ̀kan nínú àwọn ọkùnrin rẹ bá jẹ́ aláìmọ́ nítorí ìtújáde tí ó ní, o ní láti jáde kúrò nínú àgọ́, kí o má ṣe wọ inú àgọ́.

11. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá di ìrọ̀lẹ́ o ní láti wẹ ara rẹ, àti ní àṣálẹ́ kí o padà sínú àgọ́.

12. Sàmì sí ibìkan lóde àgọ́, níbi tí o lè máa lọ láti dẹ ara rẹ lára.

13. Ìwọ yóò mú igi pẹ̀lú ohun ìjà rẹ àti nígbà tí o bá dẹ ara rẹ lára tán, gbẹ́ kòtò kí o sì bo ìgbẹ́ rẹ.

14. Nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń rìn láàrin àgọ́ láti dáàbò bò ọ́ àti láti fi àwọn ọ̀taà rẹ lé ọ lọ́wọ́. Àgọ́ ọ rẹ ní láti jẹ́ mímọ́, nítorí kí ó má ba à rí ohun àìtọ́ láàrin yín kí ó sì yípadà kúrò lọ́dọ̀ ọ yín.

15. Bí ẹrú kan bá ti gba ààbò lọ́dọ̀ rẹ, má ṣe fi lé ọ̀gá rẹ̀ lọ́wọ́.

16. Jẹ́ kí ó máa gbé láàrin rẹ níbikíbi tí ó bá fẹ́ àti èyíkéyí ìlú tí ó bá mú. Má se ni í lára.

17. Kí ọkùnrin tàbí obìnrin Ísírẹ́lì má ṣe padà di alágbérè ojúbọ òrìṣà.

18. O kò gbọdọ̀ mú owó iṣẹ́ panṣágà obìnrin tàbí ọkùnrin wá sí ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ láti fi san ẹ̀jẹ́ kankan; nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ korìíra àwọn méjèèjì.

Ka pipe ipin Deutarónómì 23