Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 20:9-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Nígbà tí olórí ogun bá ti dákẹ́ ọ̀rọ̀ sísọ sí àwọn ènìyàn, wọn yóò yan olórí ogun lórí i rẹ̀.

10. Nígbà tí ó bá sún mọ́ iwájú láti dojú kọ ìlú kan láti bá a jà, nígbà náà ni kí ó fi àlàáfíà lọ̀ ọ́.

11. Tí wọ́n bá gbà tí wọ́n sì sí ìlẹ̀kùn, gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ yóò máa jẹ́ olùsìn fún ọ, wọn ó sì máa sìn ọ́.

12. Tí wọ́n bá kọ̀ láti bá ọ ṣe àlàáfíà ṣùgbọ́n tí wọ́n bá gbógun tì ọ́, nígbà náà ni kí ìwọ gbà á.

13. Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá fi lé ọ lọ́wọ́, ẹ pa gbogbo àwọn ọkùnrin tí ó wà níbẹ̀.

14. Ní ti obìnrin, àwọn ọmọdé, ohun ọ̀sìn àti gbogbo ohun tí ó kù nínú ìlú náà, o lè mú ìwọ̀nyí gẹ́gẹ́ bí ìkógún fún ara rẹ. O sì lè lo ìkógún tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ láti ọ̀dọ̀ àwọn ọ̀ta rẹ.

15. Báyìí ni ìwọ yóò ṣe sí gbogbo ìlú tí wọ́n wà ní ọ̀nà jínjìn sí ọ tí wọn kò sì tara àwọn orílẹ̀ èdè tí ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀ rẹ.

16. Ṣùgbọ́n, nínú àwọn ìlú ti àwọn orílẹ̀ èdè tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún, má ṣe dá ohun ẹlẹ́mìí kankan sí.

17. Pa wọ́n run pátapáta, àwọn ọmọ Hítì, ọmọ Ámórì, ọmọ Kénánì, ọmọ Pérísì, ọmọ Hífì, ọmọ Jébúsì gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti pa á láṣẹ fún ọ.

18. Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, wọn yóò kọ́ ọ láti tẹ̀lé gbogbo ohun ìríra tí wọ́n ń ṣe nínú sísin àwọn ọlọ́run wọn, ìwọ yóò sì sẹ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ.

19. Nígbà tí o bá dóti ìlú kan láti ọjọ́ pípẹ́, ẹ bá wọn jà láti gbà á, má ṣe pa àwọn igi ibẹ̀ run nípa gbígbé àáké lé wọn, nítorí o lè jẹ èso wọn. Má se gé wọn lulẹ̀. Nítorí igi ìgbẹ́ ha á ṣe ènìyàn bí, tí ìwọ ó máa dọ̀tí rẹ̀.

20. Ṣùgbọ́n o lè gé àwọn igi tí o mọ̀ pé wọn kì í ṣe igi eléṣo lulẹ̀ kí o sì lò wọ́n láti kọ́ ìṣọ́ sí ìlú tí ó ń bá ọ jagun, títí tí yóò fi ṣubú.

Ka pipe ipin Deutarónómì 20