Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 2:4-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Fún àwọn ènìyàn náà ní àwọn òfin wọ̀nyí: ‘Ẹ ti fẹ́ la ilẹ̀ àwọn arákùnrin yín kọjá, àwọn ọmọ Ísọ̀; àwọn ará Édómù tí ń gbé ní Séírì. Ẹ̀rù yín yóò bà wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ ṣọ́ra gidigidi.

5. Ẹ má ṣe wá wọn níjà torí pé èmi kò ní fún un yín ní èyíkéyìí nínú ilẹ̀ wọn. Bí o ti wù kí ó kéré mọ èmi kò ní fún un yín. Mo ti fi ilẹ̀ òkè Séírì fún Ísọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀.

6. Ẹ san owó oúnjẹ tí ẹ bá jẹ fún wọn àti omi tí ẹ bá mu.’ ”

7. Olúwa Ọlọ́run yín ti bùkún un yín nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ yín. Ó ti mójú tó ìrìnàjò yín nínú ihà ńlá yìí. Olúwa Ọlọ́run yín wà pẹ̀lú u yín ní ogojì ọdún wọ̀nyí, débi pé ẹ̀yin kò ṣaláìní ohunkóhun.

8. Bẹ́ẹ̀ ni a kọjá ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin wa, àwọn ọmọ Ísọ̀ tí ń gbé ní Séírì. A yà kúrò ní ọ̀nà aginjù èyí tí ó wá láti Élátì àti Ésíóni-Gébérì, a sì rìn gba ọ̀nà ihà Móábù.

9. Olúwa sì sọ fún mi pé, “Ẹ má ṣe dẹ́rùba àwọn ará Móábù bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe bá wọn jagun torí pé n kò ní fi èyíkéyìí nínú ilẹ̀ wọn fún un yín. Mo ti fi Árì fún àwọn ọmọ Lọ́tì bí i ìní.”

10. Àwọn Émímù ti gbé ibẹ̀ rí: Àwọn ènìyàn tó sígbọnlẹ̀ tó sì pọ̀, wọ́n ga bí àwọn Ánákì.

11. Gẹ́gẹ́ bí Ánákì àwọn ènìyàn náà pè wọ́n ní ará Ráfátì ṣùgbọ́n àwọn ará Móábù pè wọ́n ní Émímù.

12. Àwọn ará Hórì gbé ní Séírì kí àwọn ọmọ Ísọ̀ tó lé wọn kúrò níwájú wọn, wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn, (wọ́n tẹ̀dó sí àyè wọn) gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ṣe ní ilẹ̀ tí Olúwa yóò fún wọn ní ìní wọn.

Ka pipe ipin Deutarónómì 2