Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 2:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà ni a yípadà, tí a sì mú ọ̀nà wa pọ̀n lọ sí ihà, a gba ọ̀nà òkun pupa, bí Olúwa ti darí mi. Ìgbà pípẹ́ ni a fi ń rìn kiri yíká agbègbè àwọn ìlú olókè Séírì.

2. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún mi pé,

3. “Ẹ ti rìn yí agbégbé ilẹ̀ olókè yìí pẹ́ tó, nísinsin yìí, ẹ yípadà sí ìhà àríwá.

4. Fún àwọn ènìyàn náà ní àwọn òfin wọ̀nyí: ‘Ẹ ti fẹ́ la ilẹ̀ àwọn arákùnrin yín kọjá, àwọn ọmọ Ísọ̀; àwọn ará Édómù tí ń gbé ní Séírì. Ẹ̀rù yín yóò bà wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ ṣọ́ra gidigidi.

5. Ẹ má ṣe wá wọn níjà torí pé èmi kò ní fún un yín ní èyíkéyìí nínú ilẹ̀ wọn. Bí o ti wù kí ó kéré mọ èmi kò ní fún un yín. Mo ti fi ilẹ̀ òkè Séírì fún Ísọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ̀.

6. Ẹ san owó oúnjẹ tí ẹ bá jẹ fún wọn àti omi tí ẹ bá mu.’ ”

7. Olúwa Ọlọ́run yín ti bùkún un yín nínú gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ ọ yín. Ó ti mójú tó ìrìnàjò yín nínú ihà ńlá yìí. Olúwa Ọlọ́run yín wà pẹ̀lú u yín ní ogojì ọdún wọ̀nyí, débi pé ẹ̀yin kò ṣaláìní ohunkóhun.

8. Bẹ́ẹ̀ ni a kọjá ọ̀dọ̀ àwọn arákùnrin wa, àwọn ọmọ Ísọ̀ tí ń gbé ní Séírì. A yà kúrò ní ọ̀nà aginjù èyí tí ó wá láti Élátì àti Ésíóni-Gébérì, a sì rìn gba ọ̀nà ihà Móábù.

Ka pipe ipin Deutarónómì 2