Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 16:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ kíyèsí oṣù Ábíbù, kí ẹ sì máa ṣe àjọ̀dún ìrékọjá ti Olúwa Ọlọ́run yín, nítorí pé ní oṣù Ábíbù yìí ni ó mú un yín jáde ní Éjíbítì lóru.

2. Ẹ fi ẹran kan rúbọ bí ìrékọjá sí Olúwa Ọlọ́run yín láti inú ọ̀wọ́ ẹran tàbí agbo màlúù yín ní ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn bí ibùgbé fún orúkọ rẹ̀.

3. Ẹ má ṣe jẹ ẹ́ pẹ̀lú u àkàrà tí a fi ìwúkàrà ṣe, ṣùgbọ́n ọjọ́ méje ni kí ẹ fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà, àkàrà ìpọ́njú, nítorí pé pẹ̀lú ìkánjú ni ẹ kúrò ní Éjíbítì: kí ẹ báà lè rántí ìgbà tí ẹ kúrò ní Éjíbítì ní gbogbo ọjọ́ ayé e yín.

4. Kí a má ṣe rí ìwúkàrà ní ọ̀dọ̀ ọ yín nínú ilẹ̀ ẹ yín fún ọjọ́ méje. Ẹ má ṣe jẹ́ kí nǹkan kan sẹ́kù nínú ẹran tí ẹ ó fi rúbọ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kìn-ín-ní di àárọ̀ ọjọ́ kéjì.

5. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe ìrékọjá náà ní ìlúkílùú kankan, tí Olúwa Ọlọ́run yín fi fún un yín

6. bí kò ṣe ibi tí yóò yàn gẹ́gẹ́ bí ibùgbé fún orúkọ rẹ̀, níbẹ̀ ni ki ẹ ti ṣe ìrúbọ ìrékọjá náà ní ìrọ̀lẹ́ nígbà tí òòrùn bá ń wọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìránti ìgbà tí ẹ kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì.

7. Ẹ ṣun ún kí ẹ sì jẹ ẹ́ ní ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn. Ní àárọ̀, kí ẹ padà sí àgọ́ ọ yín.

8. Ọjọ́ mẹ́fà ní kí ẹ fí jẹ àkàrà aláìwú, ní ọjọ́ kéje, ẹ pe àjọ kan fún Olúwa Ọlọ́run yín, kí ẹ má sì ṣe iṣẹ́ kankan.

Ka pipe ipin Deutarónómì 16