Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 12:2-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Gbogbo ibi gíga àwọn òkè ńlá, àti òkè kéékèèkéé àti lábẹ́ gbogbo igi tí ń gbilẹ̀ níbi tí àwọn orílẹ̀ èdè tí ẹ ó lé jáde, tí ń sin òrìṣà wọn ní kí ẹ mú kúrò pátapáta.

3. Ẹ wó àwọn pẹpẹ wọn, ẹ bi òpó ìsìn wọn subú, kí ẹ sì sun òpó òrìṣà wọn ní iná. Ẹ gé gbogbo ère òrìṣà wọn lulẹ̀, kí ẹ sì pa orúkọ wọn rẹ́ ní gbogbo ààyè wọn.

4. Ẹ kò gbọdọ̀ sin Olúwa Ọlọ́run yín bí i tiwọn.

5. Ṣùgbọ́n ẹ wá ibi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn láàrin àwọn ìran yín, láti fi orúkọ rẹ̀ ṣíbẹ̀ bí i ibùgbé rẹ̀. Ibẹ̀ ni kí ẹ lọ.

6. Níbẹ̀ ni kí ẹ mú ọrẹ síṣun àti ẹbọ yín wá, ìdámẹ́wàá yín àti ọrẹ àkànṣe, àwọn ẹ̀jẹ́ yín, ọrẹ àtinúwá yín, àti àwọn àkọ́bí gbogbo màlúù yín àti ewúrẹ́ ẹ yín.

7. Níwájú Olúwa Ọlọ́run yín níbẹ̀, kí ẹ̀yin àti ìdílé yín jẹun kí ẹ sì yó, nínú gbogbo ìdáwọ́lé e yín, torí pé Olúwa Ọlọ́run yín ti bùkún un yín.

8. Ẹ má ṣe ṣe bí a tí ṣe lónìí yìí, tí olúkúlùkù ń ṣe ohun tí ó wù ú.

9. Níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti dé ibi ìsinmi, àti ibi ogún tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín.

10. Ṣùgbọ́n ẹ ó la Jọ́dánì kọjá, ẹ ó sì máa gbé ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín fún un yín bí ìní, yóò sì fún un yín ní ìsinmi, kúrò láàrin àwọn ọ̀ta a yín, tí ó yí i yín ká, kí ẹ báà lè máa gbé láìléwu.

11. Níbi tí Olúwa Ọlọ́run yín yóò yàn bí ibùgbé fún orúkọ rẹ̀. Níbẹ̀ ni kí ẹ mú gbogbo ohun tí mo pàṣẹ fún un yín wá: àwọn ọrẹ ẹ yín àti àwọn ẹbọ síṣún, ìdámẹ́wàá yín àti ọrẹ àkànṣe, àti gbogbo ohun ìní yín tí ẹ ti yàn, èyí tí ẹ ti jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Olúwa.

12. Kí ẹ máa yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run yín níbẹ̀, ẹ̀yin, àwọn ọmọkùnrin yín, àwọn ọmọbìnrin yín, ìránṣẹ́-bìnrin àti ìránṣẹ́-kùnrin yín, àti àwọn Léfì láti ìlú u yín, tí wọn kò ní ìpín tàbí ogún tiwọn.

Ka pipe ipin Deutarónómì 12