Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Deutarónómì 11:17-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Nígbà náà ni ìbínú Olúwa yóò sì ru sí i yín, Òun yóò ti ìlẹ̀kùn ọ̀run kí òjò má baà rọ̀, ilẹ̀ kì yóò sì so èso kankan, ẹ ó sì ṣègbé ní ilẹ̀ rere tí Olúwa fi fún un yín.

18. Ẹ fi gbogbo ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí sí àyà a yín, àti ọkàn an yín, ẹ so wọ́n bí àmì sórí ọwọ́ ọ yín, kí ẹ sì ṣo wọ́n mọ́ iwájú orí i yín.

19. Ẹ máa fí wọ́n kọ́ àwọn ọmọ yín, ẹ máa sọ̀rọ̀ nípa wọn bí ẹ bá jókòó nínú ilé, àti ní ojú ọ̀nà bí ẹ bá ń rìn lọ, bí ẹ bá sùn àti bí ẹ bá jí.

20. Ẹ kọ wọ́n sí férémù ìlẹ̀kùn yín, àti ẹnu ọ̀nà àbáwọlé e yín.

21. Kí ọjọ́ ọ yín àti ti àwọn ọmọ yín lè pọ̀ ní ilẹ̀ tí Olúwa ti búra láti fifún àwọn baba ńlá a yín, ní ìwọ̀n ìgbà tí ọ̀run wà lókè tí ayé sì ń bẹ ní ìṣàlẹ̀.

22. Bí ẹ bá farabalẹ̀ kíyèsí àwọn òfin tí mo ń fún un yín, láti tẹ̀lé: Láti fẹ́ Olúwa Ọlọ́run yín, láti máa rìn ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀ àti láti dìí mú ṣinṣin:

23. Olúwa yóò sì lé gbogbo orílẹ̀ èdè wọ̀nyí kúrò níwájú u yín. Ẹ ó sì gba orílẹ̀ èdè tí ó lágbára tí ó sì tóbi jù yín lọ.

24. Gbogbo ibi tí ẹ bá fi ẹṣẹ̀ ẹ yín tẹ̀ ni yóò jẹ́ tiyín, ilẹ̀ ẹ yín yóò gbilẹ̀ láti aṣálẹ̀ dé Lẹ́bánónì, àti láti odò Yúfúrátè dé òkun ìwọ̀ oòrùn.

25. Kò sí ẹni náà tí yóò lè kò yín lójú ìjà, Olúwa Ọlọ́run yín yóò fi ẹ̀rù àti ìwárìrì i yín sórí gbogbo ilẹ̀ náà bí ó ti ṣèlérí fún un yín ní gbogbo ibi tí ẹ bá lọ.

26. Ẹ kíyèsí i, mo fi ìbùkún àti ègún lélẹ̀ níwájú u yín lónìí:

27. ìbùkún ni, bí ẹ bá pa òfin Olúwa Ọlọ́run yín, tí mo ń fún un yín lónìí mọ́.

28. Ègún ni, bí ẹ bá ṣàìgbọ́ràn, sí òfin Olúwa Ọlọ́run yín, tí ẹ sì yapa kúrò ní ọ̀nà tí mo ti là sílẹ̀ fún yín lónìí, nípa títẹ̀lé ọlọ́run mìíràn, tí ẹ kò tíì mọ̀.

Ka pipe ipin Deutarónómì 11