Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dáníẹ́lì 8:9-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Lára ọ̀kan nínú un wọn, ìwo mìíràn yọ jáde, ó kékeré, ṣùgbọ́n ó dàgbà nínú agbára sí ìhà gúsù, àti sí ìhà ìlà oòrun àti sí ilẹ̀ dídára.

10. Ó sì dàgbà títí ó fi kan ẹgbẹ́ ogun ọ̀run, ó sì jù lára àwọn ẹgbẹ́ ogun ọ̀run sí ayé ó sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀,

11. ó sì gbé ara rẹ̀ ga gẹ́gẹ́ bí ọmọ aládé ẹgbẹ́ ogun ọ̀run; ó sì mú ẹbọ ojoojúmọ́ kúrò lọ́dọ̀ ọ rẹ̀, ó sì gba àyè ibi mímọ́ rẹ̀.

12. A fún-un ní ẹgbẹ́ ogun ọ̀run àti ẹbọ ojojúmọ́ nítorí ìwà ọlọ̀tẹ̀ ẹ rẹ̀: ó sọ òtítọ́ nù nínú gbogbo ohun tó ṣe.

13. Nígbà náà, ni mo gbọ́ tí ẹni mímọ́ ń sọ̀rọ̀, àti ẹni mímọ́ mìíràn sọ̀rọ̀ fún-un pé, “Yóò ti pẹ́ tó tí ìran yìí yóò fi wá sí ìmúsẹ-ìran nípa ẹbọ ojojúmọ́, ìṣọ̀tẹ̀ tí ó ń sọ dahoro, àti mímú kí ibi mímọ́ àti ẹgbẹ́ ogun ọ̀run di ìtẹ̀mọ́lẹ̀?”

14. Ó sọ fún mi pé, “Yóò gbà tó ẹgbọ̀kànlá lé lọ́gọ́rùn-ún (2,300) alẹ́ àti òwúrọ̀; lẹ́yìn náà ni a ó tún ibi mímọ́ yà sí mímọ́.”

15. Nígbà tí èmi Dáníẹ́lì, ń wo ìran náà, mo sì ń fẹ́ kí ó yé mi, ẹnìkan tí ó sì dúró níwájú ù mi.

16. Mo gbọ́ ohùn ènìyàn ní ẹ̀gbẹ́ Úláì, tí ó ń pè pẹ́ “Gébúrẹ́lì, sọ ìtumọ̀ ìran náà fún ọkùnrin yìí.”

17. Bí ó ṣe súnmọ́ ibi tí mo dúró sí, ẹ̀rù bàmí, mo sì dọ̀bálẹ̀. Ó ń sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, jẹ́ kí ó yé ọ pé ìran náà ń sọ nípa ìgbà ìkẹyìn ni.”

Ka pipe ipin Dáníẹ́lì 8