Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dáníẹ́lì 4:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nebukadinésárì ọba,Sí gbogbo ènìyàn, orílẹ̀ àti onírúurú èdè, tí ó ń gbé ní àgbáyé:Kí Àlàáfíà máa pọ̀ síi fún un yín.Kí ẹ ṣe rere tó pọ̀!

2. Ó jẹ́ ìdùnnú fún mi láti fi iṣẹ́ àmì àti ìyanu tí Ọlọ́run Ọ̀gá Ògo ti ṣe fún mi hàn.

3. Báwo ni àmì rẹ̀ ti tóbi tó,Báwo ni ìyanu rẹ̀ ṣe pọ̀ tó!Ìjọba rẹ̀, ìjọba títí ayé ni;ilẹ̀ ọba rẹ̀ láti ìran dé ìran ni.

4. Èmi Nebukadinéṣárì wà ní ààfin mi, pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn àti àlàáfíà.

5. Mo lá àlá kan èyí tí ó bà mí lẹ́rù. Nígbà tí mo wà lórí ibùṣùn mi, ìran tí ó jáde lọ́kàn mi dẹ́rù bà mí.

6. Nígbà náà, ni mo pàṣẹ pé kí a mú gbogbo àwọn amòye Bábílónì wá, kí wọn wá sọ ìtumọ̀ àlá náà fún mi.

7. Nígbà tí àwọn onídán, àwọn apògèdè, àwọn awòràwọ̀ àti àwọn aláfọ̀ṣẹ wá, mo sọ àlá náà fún wọn, ṣùgbọ́n wọn kò le è sọ ìtúmọ̀ àlá náà fún mi.

8. Ní ìkẹyìn Dáníẹ́lì wá síwájú mi, mo sì sọ àlá náà fún (ẹni tí à ń pè ní Beliteṣáṣárì gẹ́gẹ́ bí orúkọ òrìṣà mi àti pé ẹ̀mí àwọn Ọlọ́run mímọ́ wà nínú un rẹ̀.)

9. Mo wí pé, “Beliteṣásárì, olórí àwọn amòye, èmi mọ̀ wí pé ẹ̀mí Ọlọ́run mímọ́ wà nínú rẹ, kò sì sí àsírí kan tí ó ṣòro jù fún ọ. Sọ àlá mi kí o sì túmọ̀ rẹ̀ fún mi.

Ka pipe ipin Dáníẹ́lì 4