Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ámósì 7:8-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Olúwa sì bi mi pé, “Ámósì, kí ni ìwọ rí?”Mo dáhùn pé, “Okùn-ìwọ̀n.”Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Wòó, Èmí ń gbé okùn-ìwọ̀n kalẹ láàárin àwọn Ísírẹ́lì ènìyàn mi; Èmi kì yóò sì tún kọjá lọ́dọ̀ wọn mọ́

9. “Ibi gíga Ísáákì wọ̀n-ọn-nì yóò sì di ahoroàti ibi mímọ Ísírẹ́lì wọ̀n-ọn-nì yóò di ahoro.Èmi yóò sì fi idà dide sí ilé Jéróbóámù.”

10. Nígbà náà Ámásáyà àlùfáà Bẹ́tẹ́lì ránṣẹ́ sí Jéróbóámù ọba Ísírẹ́lì, wí pé: “Ámosì ti dìde láti dìtẹ̀ sí ọ ni àárin gbùngbùn Ísírẹ́lì. Ilẹ̀ kò sì le gba gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀.

11. Nítorí èyí ni ohun ti Ámosì ń sọ:“ ‘Jéróbóámù yóò ti ipa idà kú,Lóótọ́ Ísírẹ́lì yóò lọ sí ìgbèkùn,jìnnà kúrò ní ilẹ̀ ìní wọn.’ ”

12. Nígbà náà ni Ámásáyà sọ fún Ámósì pé “Lọ jáde, ìwọ aríran! Padà sí ilẹ̀ àwọn Júdà. Kí o máa jẹun rẹ níbẹ̀ ki o sì sọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ níbẹ̀.

13. Má ṣe sọtẹ́lẹ̀ mọ ni Bẹ́tẹ́lì nítorí ibi mímọ́ ọba ni àti ibi tẹ́ḿpìlì ìjọba rẹ̀.”

Ka pipe ipin Ámósì 7