Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ámósì 4:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ẹ̀yin màlúù Báṣánì lórí òkè Samáríà,ẹ̀yin obìnrin tí ó ń ni talákà lára,tí ó ń tẹ aláìní mọ́lẹ̀, tí ó wí fún ọkọ rẹ̀, “Gbé wá kí a sì mu!”

2. Olúwa Ọlọ́run ti fi ìwà mímọ́ rẹ̀ búra:“Àkókò náà yóò dé nítòótọ́nígbà tí a ó fi ìwọ̀ mú un yín lọ,ẹni tí ó kẹ́yìn pẹ̀lú ìwọ̀ ẹja.

3. Ẹni kọ̀ọ̀kan yín yóò jáde lọgba àárin odi yíyaa ó sì lé e yín sí Hámónà,”ni Olúwa wí.

4. “Ẹ lọ sí Bétélì láti dẹ́ṣẹ̀;ẹ lọ sí Gílígálì kí ẹ sì dẹ́ṣẹ̀ sí i.Ẹ mú ẹbọ sísun yín láràárọ̀ wá,ìdámẹ́wàá yín ní ọdọdún mẹ́ta.

5. Kí ẹ mú ọrẹ́ ìdúpẹ́ ìyẹ̀fun tí a sunkí ẹ sì mú ọrẹ àtinúwálọ fi wọ́n yagàn, ẹ̀yin ènìyàn Ísírẹ́lì,nítorí èyí ni ẹ fẹ́ láti ṣe,”ni Olúwa Ọlọ́run wí.

6. “Èmi fún un yín ní inú òfìfo ní gbogbo ìlúàti láìní àkàrà ní gbogbo ibùgbé yín,ṣíbẹ̀, ẹ̀yin kò tí ì yípadà sími,”ni Olúwa wí.

7. “Àti pẹ̀lú mo mú òjò dúrónígbà tí ìkórè ku oṣù mẹ́ta.Mo rán òjò sí ibùgbé kanṣùgbọ́n kò rọ̀ sí ìlú mìíràn.Oko kan ní òjò;àwọn mìíràn kò ní ó sì gbẹ.

8. Àwọn ènìyàn ń rìn láti ìlú kan sí ibòmíràn fún omiwọn kò rí àrító láti mú,ṣíbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi,”ni Olúwa wí.

9. “Lọ́pọ̀ ìgbà ni mo lu ọgbà àti ọgbà àjàrà yínmo fi àrá àti ìrì lù wọ́n.Esú sì jẹ igi ọ̀pọ̀tọ́ àti igi ólífì yín,ṣíbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi,”ni Olúwa wí.

10. “Mo rán àjàkálẹ̀-àrùn sí i yínbí mo ti ṣe sí Éjíbítì.Mo fi idà pa àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín.Pẹ̀lú àwọn ẹṣin tí a kó ní ìgbékùn.Mo kún imú yín fún òórùn ibùdó yín,síbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi,”ni Olúwa wí.

11. “Mo ti bì ṣubú nínú yín,bí Ọlọ́run ti bi Sódómù àti Gòmórà ṣubúẹ̀yin sì dàbí ògúnná tí a fò yọ kúrò nínú ìjóná,ṣíbẹ̀ ẹ̀yin kò yípadà sí mi,”ni Olúwa wí.

Ka pipe ipin Ámósì 4