Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ámósì 2:11-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Èmi sì tún gbé àwọn wòlíì dìde láàárin àwọn ọmọ yínàti láàárin àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín láti jẹ Násárátìèyí kò ha jẹ́ òtítọ́ bí ará Ísírẹ́lì?”ni Olúwa wí.

12. “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin fún àwọn Násárátì ní ọtí muẸ sì pàṣẹ fún àwọn wòlíì kí wọ́n má ṣe sọ tẹ́lẹ̀.

13. “Ní báyìí, èmi yóò tẹ̀ yín mọ́lẹ̀bí kẹ̀kẹ́ tí ó kún fún ìtí ti í tẹ̀.

14. Ẹni tí ó yára bí àṣá kò ní rí ọ̀nà àbáyọalágbára kò ní le è dúró lé agbára rẹ̀jagunjagun kì yóò le gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là

15. tafàtafà kì yóò dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó gún ẹṣinkì yóò gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là

16. àní jagunjagun tí ó gbóyà jùlọyóò sálọ ní ìhòòhò ní ọjọ́ náà,”ni Olúwa wí.

Ka pipe ipin Ámósì 2