Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 7:8-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. nítorí Dámásíkù ni orí Árámù,orí Dámásíkù sì ni Résínì.Láàrin ọdún márùnlélọ́gọ́taÉfáímù yóò ti fọ́ tí kì yóò le jẹ́ ènìyàn mọ́.

9. Ṣamaríà ni orí fún Éfáímù,ẹni tí ó sì jẹ́ orí Samaríà náà ni ọmọ Rèmálíà.’ ”

10. Bákan náà Olúwa tún bá Áhásì sọ̀rọ̀,

11. “Béèrè fún ààmì lọ́wọ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, bóyá ní ọ̀gbun tí ó jìn jùlọ tàbí àwọn òkè tí ó ga jùlọ”

12. Ṣùgbọ́n Áhásì sọ pé, “Èmi kì yóò béèrè; Èmi kò ní dán Olúwa wò.”

13. Lẹ́yìn náà Àìṣáyà sọ pé, “Gbọ́ ní ìsinsìnyí, ìwọ ilé Dáfídì, kò ha tọ́ láti tan ènìyàn ní ṣùúrù, o ó ha tan Ọlọ́run ní ṣùúrù bí?

14. Nítorí náà, Olúwa fúnra ara rẹ̀ ni yóò fún ọ ní àmì kan. Wúndíá kan yóò lóyún, yóò sì bí ọmọkùnrin kan, yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Ìmánúẹ́lì.

15. Òun yóò jẹ wàrà àti oyin nígbà tí ó bá ní ìmọ̀ tó láti kọ ẹ̀bi àti láti yan àre.

16. Ṣùgbọ́n kí ọ̀dọ́mọkùnrin náà tó mọ bí a ti ń kọ ẹ̀bi àti láti yan àre, ilẹ̀ àwọn ọba méjèèjì tí ń bà ọ́ lẹ́rù wọ̀nyí yóò ti di ahoro.

17. Olúwa yóò mú àsìkò mìíràn wá fún ọ àti àwọn ènìyàn rẹ àti lórí ilé baba rẹ irú èyí tí kò sí láti ìgbà tí Éfáímù ti yà kúrò ní Júdà, yóò sì mú ọba Áṣíríà wá.”

18. Ní ọjọ́ náà ni Olúwa yóò súfèé pe àwọn eṣinṣin láti àwọn odò tó jìnnà ní Éjíbítì wá, àti fún àwọn oyin láti ilẹ̀ Áṣíríà.

19. Gbogbo wọn yóò sì wá dó sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè àti pàlàpálá òkúta, lára koríko ẹ̀gún àti gbogbo ibi ihò omi.

20. Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò lo abẹfẹ́lẹ́ tí a yá láti ìkọjá odò, ọba Ásíríà, láti fá irun orí àti ti àwọn ẹsẹ̀ẹ yín, àti láti mú irùngbọ̀n yín kúrò pẹ̀lú.

21. Ní ọjọ́ náà, ọkùnrin kan yóò máa sin ọ̀dọ́ màlúù kan àti ewúrẹ́ méjì.

22. Àti nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàrà tí wọn yóò máa fún un, yóò ní wàràǹkàsì láti jẹ. Gbogbo àwọn tí ó bá kù ní ilẹ̀ náà yóò jẹ wàràǹkàsì àti oyin.

Ka pipe ipin Àìsáyà 7