Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 7:20-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Ní ọjọ́ náà, Olúwa yóò lo abẹfẹ́lẹ́ tí a yá láti ìkọjá odò, ọba Ásíríà, láti fá irun orí àti ti àwọn ẹsẹ̀ẹ yín, àti láti mú irùngbọ̀n yín kúrò pẹ̀lú.

21. Ní ọjọ́ náà, ọkùnrin kan yóò máa sin ọ̀dọ́ màlúù kan àti ewúrẹ́ méjì.

22. Àti nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàrà tí wọn yóò máa fún un, yóò ní wàràǹkàsì láti jẹ. Gbogbo àwọn tí ó bá kù ní ilẹ̀ náà yóò jẹ wàràǹkàsì àti oyin.

23. Ní ọjọ́ náà, ni gbogbo ibi tí àjàrà tí ó tó ti ẹgbẹ̀rún ṣékélì fàdákà, ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n nìkan ni yóò wà níbẹ̀.

24. Àwọn ènìyàn yóò máa lọ ṣíbẹ̀ pẹ̀lú ọrun àti ọfà nítorí pé ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n ni yóò bo gbogbo ilẹ̀ náà.

25. Fún àwọn òkè tí a ti ń fi ọkọ́ ro nígbà kan rí, ẹ kò ní lọ ṣíbẹ̀ mọ́ nítorí ìbẹ̀rù ẹ̀gún àti ẹ̀wọ̀n, wọn yóò di ibi tí a ń tú agbo ẹran sí, àti ibi tí àwọn àgùntàn ti ń sáré.

Ka pipe ipin Àìsáyà 7