Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 66:6-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Gbọ́ rògbòdìyàn n nì láti ìlú wá,gbọ́ ariwo náà láti tẹ́ḿpìlì wá!Ariwo tí Olúwa ní í ṣetí ó ń san án fún àwọn ọ̀ta rẹ̀ ohuntí ó tọ́ sí wọn.

7. “Kí ó tó lọ sí ìrọbí,ó ti bímọ;kí ó tó di pé ìrora dé bá a,ó ti bí ọmọkùnrin.

8. Ta ni ó ti gbọ́ irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí?Ta ni ó ti rí irú nǹkan bẹ́ẹ̀ rí?Ǹjẹ́ a le bí orílẹ̀ èdè kan níjọ́ kantàbí kí orílẹ̀ èdè lalẹ̀hù ní ìṣẹ́jú kan?Síbẹ̀síbẹ̀ Ṣíhónì bẹ̀rẹ̀ rírọbí tàìrọbíbẹ́ẹ̀ ni ó sì bí àwọn ọmọ rẹ̀.

9. Ǹjẹ́ èmi a ha máa mú wá sí ìrọ́bíkí èmi má sì mú ni bí?” ni Olúwa wí.“Ǹjẹ́ èmi a ha máa ṣé ilé ọmọnígbà tí mo ń mú ìbí wá?” ni Ọlọ́run yín wí.

10. “Ẹ bá Jérúsálẹ́mù yọ̀ kí inú yín kí ó sì dùn sí i,gbogbo ẹ̀yin tí ẹ fẹ́ràn rẹ̀;ẹ yọ̀ gidigidi pẹ̀lú rẹ̀,gbogbo ẹ̀yin tí ó ti kẹ́dùn fún un.

11. Nítorí pé ẹ̀yin yóò mu ẹ o sì ní ìtẹ́lọ́rùnnínú ọmú rẹ̀ tí ó túnilára;Ẹ̀yin yóò mu àmuyóẹ ó sì gbádùn nínú à-kún-wọ́-sílẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ rẹ̀.”

12. Nítorí ohun tí Olúwa wí nìyìí:“Èmi yóò fún un ní àlàáfíà gẹ́gẹ́ bí odòàti ọrọ̀ orílẹ̀ èdè gẹ́gẹ́ bí ìṣàn omi;ẹ̀yin yóò mu ọmú, a ó sì gbé yín ní apá rẹ̀a ó bá yín ṣeré ní orúkún rẹ̀.

13. Gẹ́gẹ́ bí ìyá ti í tu ọmọ rẹ̀ nínú,bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò tù yín nínúa ó sì tù yín nínú lórí Jérúsálẹ́mù.”

14. Nígbà tí ẹ bá rí èyí, inú un yín yóò dùnẹ̀yin yóò sì gbilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i koríko;ọwọ́ Olúwa ni a ó sọ di mímọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀,ṣùgbọ́n ìbínú rẹ̀ ni a ó fihàn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.

15. Kíyèsí i, Olúwa ń bọ̀ pẹ̀lú ináàti kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ tí ó dàbí ìjì líle;òun yóò mú ìbínú rẹ ṣọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ìrunú,àti ìbáwí rẹ̀ pẹ̀lú ahọ́n iná.

16. Nítorí pẹ̀lú iná àti idàni Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ lóríi gbogbo ènìyàn,àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí Olúwa yóò pa.

17. “Gbogbo àwọn tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ tí wọ́n sì sọ ara wọn di mímọ́ láti lọ sínú ọgbà, tí wọ́n tẹ̀lé ẹni tí ó wà láàrin àwọn tí ó jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀ àti èkúté àti àwọn ohun ìríra mìíràn ni wọn yóò bá òpin wọn pàdé papọ̀,” ni Olúwa wí.

18. “Àti Èmi, nítorí ìgbéṣẹ̀ wọn àti èrò wọn, èmi ti múra tán láti wá kó àwọn òrílẹ̀ èdè àti ahọ́n jọ, wọn yóò sì wá wo ògo mi.

Ka pipe ipin Àìsáyà 66