Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 66:12-24 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Nítorí ohun tí Olúwa wí nìyìí:“Èmi yóò fún un ní àlàáfíà gẹ́gẹ́ bí odòàti ọrọ̀ orílẹ̀ èdè gẹ́gẹ́ bí ìṣàn omi;ẹ̀yin yóò mu ọmú, a ó sì gbé yín ní apá rẹ̀a ó bá yín ṣeré ní orúkún rẹ̀.

13. Gẹ́gẹ́ bí ìyá ti í tu ọmọ rẹ̀ nínú,bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò tù yín nínúa ó sì tù yín nínú lórí Jérúsálẹ́mù.”

14. Nígbà tí ẹ bá rí èyí, inú un yín yóò dùnẹ̀yin yóò sì gbilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i koríko;ọwọ́ Olúwa ni a ó sọ di mímọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀,ṣùgbọ́n ìbínú rẹ̀ ni a ó fihàn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.

15. Kíyèsí i, Olúwa ń bọ̀ pẹ̀lú ináàti kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ tí ó dàbí ìjì líle;òun yóò mú ìbínú rẹ ṣọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ìrunú,àti ìbáwí rẹ̀ pẹ̀lú ahọ́n iná.

16. Nítorí pẹ̀lú iná àti idàni Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ lóríi gbogbo ènìyàn,àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí Olúwa yóò pa.

17. “Gbogbo àwọn tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ tí wọ́n sì sọ ara wọn di mímọ́ láti lọ sínú ọgbà, tí wọ́n tẹ̀lé ẹni tí ó wà láàrin àwọn tí ó jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀ àti èkúté àti àwọn ohun ìríra mìíràn ni wọn yóò bá òpin wọn pàdé papọ̀,” ni Olúwa wí.

18. “Àti Èmi, nítorí ìgbéṣẹ̀ wọn àti èrò wọn, èmi ti múra tán láti wá kó àwọn òrílẹ̀ èdè àti ahọ́n jọ, wọn yóò sì wá wo ògo mi.

19. “Èmi yóò sì gbé àmì kan kalẹ̀ láàrin wọn, èmi yóò sì rán díẹ̀ nínú àwọn tí ó sálà lọ sí àwọn orílẹ̀ èdè Táṣíṣì, sí àwọn ará Líbíyà àti Lídíyà (ti a mọ̀ sí atamọ́tàsé), sí Túbálì ati ará Gíríkì, àti sí àwọn erékùṣù tí ó jìnnàréré tí kò tí ìgbọ́ nípa òkìkí mi tàbí kí ó rí ògo mi. Wọn yóò kéde ògo mi láàrin àwọn orílẹ̀ èdè.

20. Wọn yóò sì mú àwọn arákùnrin yín wá, láti gbogbo orílẹ̀ èdè, sí òkè mímọ́ mi ní Jérúsálẹ́mù gẹ́gẹ́ bí ọrẹ sí Olúwa lórí ẹṣin, lórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti wágùnnù, àti lórí ìbáaka àti ràkúnmí,” ni Olúwa wí. “Wọn yóò kó wọn wá, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti mú ọrẹ oníhóró wọn wá, sínú tẹ́ḿpìlì Olúwa nínú ohun èlò mímọ́.

21. Àti pé èmi yóò sì yan àwọn kan nínú wọn pẹ̀lú láti jẹ́ àlùfáà àti Léfì,” ni Olúwa wí.

22. “Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀run tuntun àti ayé tuntun tí mo dá yóò ṣe faradà á níwájú mi,” ni Olúwa wí, “Bẹ́ẹ̀ ni orúkọ yín àti ìrandíran yín yóò pegedé.

23. Láti oṣù tuntun kan dé òmíràn àti láti ọjọ́ ìsinmi kan dé òmíràn, ni gbogbo ọmọnìyàn yóò wá, wọn yóò sì tẹríba níwájú mi,” ni Olúwa wí.

24. “Wọn yóò sì jáde lọ wọn yóò sì lọ wo òkú àwọn tí wọ́n dìtẹ̀ sí mi; kòkòrò wọn kì yóò kú, bẹ́ẹ̀ ni iná wọn ni a kì yóò pa, bẹ́ẹ̀ ni wọn yóò sì jẹ́ ohun ìríra fún gbogbo ọmọ ènìyàn.”

Ka pipe ipin Àìsáyà 66