Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 66:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ohun tí Olúwa wí nìyìí:“Ọ̀run ni ìtẹ́ mi,ayé sì ni àpótí ìtìṣẹ mi,Níbo ni ilé tí ẹ ó kọ́ fún mi wà?Níbo ní ibi ìsinmi mi yóò gbé wà?

2. Kì í ha á ṣe ọwọ́ mi ló tí ṣe nǹkan wọ̀nyí,bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì wà?”ni Olúwa wí.“Eléyìí ni ẹni tí mo kà sí:ẹni náà tí ó rẹrarẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì kẹ́dùn ní ọkàn rẹ̀,tí ó sì wárìrì nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ mi.

3. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó fi akọ màlúù rúbọó dàbí ẹni tí ó pa ènìyàn kanàti ẹni tí ó bá fi ọ̀dọ́ àgùntàn kan tọrẹ,dàbí ẹni tí ó kán ajá kan lọ́rùn;ẹnikẹ́ni tí ó bá fi irúgbin oníhóró tọrẹdàbí ẹni tí ó mú ẹ̀jẹ̀ ẹlẹ́dẹ̀ wá,ẹni tí ó bá sì ṣun tùràrí ìrántí,dàbí ẹni tí ó sin ère òrìṣà.Wọ́n ti yan ipa ọ̀nà tiwọn,ọkàn wọn pẹ̀lú sì láyọ̀ nínú ohun ìríra wọn;

4. Fún ìdí èyí ni èmi pẹ̀lú yóò ṣe fi ọwọ́ líle mú wọnn ó sì mú ohun tí wọ́n bẹ̀rù rẹ̀ wá sórí wọn.Nítorí nígbà tí mo pè, kò sí ẹni tí ó dáhùn,nígbà tí mo sọ̀rọ̀, ẹnikẹ́ni kò tẹ́tísílẹ̀.Wọ́n ṣe ohun búburú ní ojú miwọ́n sì yan ohun tí mo kóríìra rẹ̀.”

5. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa,Ẹ̀yin tí ẹ ń wárìrì nípaṣẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀:“Àwọn arákùnrin yín tí wọ́n kóríra yín,tí wọ́n ta yín nù nítorí orúkọ mi, wí pé,‘Jẹ́ kí a yin Olúwa lógo,kí a le rí ayọ̀ yín!’Ṣùgbọ́n àwọn ni ojú yóò tì.

6. Gbọ́ rògbòdìyàn n nì láti ìlú wá,gbọ́ ariwo náà láti tẹ́ḿpìlì wá!Ariwo tí Olúwa ní í ṣetí ó ń san án fún àwọn ọ̀ta rẹ̀ ohuntí ó tọ́ sí wọn.

Ka pipe ipin Àìsáyà 66