Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 65:12-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Èmi yóò yà ọ́ ṣọ́tọ̀ fún idà,àti pé ẹ̀yin yóò bẹ̀rẹ̀ mọ́lẹ̀ fún àwọn tí a pa;nítorí mo pè, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò dáhùn.Mo ṣọ̀rọ̀ ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò tẹ́tísílẹ̀Ẹ̀yin ṣe búrurú ní ojú miẹ sì yan ohun tí ó bàmí lọ́kàn jẹ́.”

13. Nítorí náà ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí nìyìí:“Àwọn ìránṣẹ́ mi yóò jẹun;ṣùgbọ́n ebi yóò máa pa ẹ̀yin,àwọn ìránṣẹ́ mi yóò mu,ṣùgbọ́n òrùngbẹ yóò máa gbẹ ẹ̀yin;àwọn ìránṣẹ́ mi yóò ṣe àjọyọ̀,ṣùgbọ́n a ó dójú ti ẹ̀yin.

14. Àwọn ìránṣẹ́ mi yóò kọrinláti inú ayọ̀ ọkàn wọn wá,ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò kígbe sókèláti inú ìrora ọkàn yínàti ìpohùnréré ní ìròbìnújẹ́ ọkàn.

15. Ẹ̀yin yóò fi orúkọ yín sílẹ̀fún àwọn àyànfẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí ègún; Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò sì pa yín,ṣùgbọ́n fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni òunyóò fún ní orúkọ mìíràn

16. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàdúrà ìbùkún ní ilẹ̀ náàyóò ṣe é nípaṣẹ̀ Ọlọ́run òtítọ́;Ẹni tí ó bá búra ní ilẹ̀ náàyóò búra nípaṣẹ̀ Ọlọ́run òtítọ́.Nítorí ìyọnu àtijọ́ yóò di ìgbàgbéyóò sì farasin kúrò lójú mi.

17. “Kíyèsí i, Èmi yóò dáàwọn ọ̀run tuntun àti ayé tuntunA kì yóò rántí ohun àtẹ̀yìnwá mọ́,tàbí kí wọn wá sí ọkàn.

18. Ṣùgbọ́n ẹ yọ̀ kí inú yín dùn títí láénínú ohun tí èmi yóò dá,nítorí èmi yóò dá Jérúsálẹ́mù láti jẹ́ ohun ìdùnnúàti àwọn ènìyàn rẹ̀, ohun ayọ̀.

19. Èmi yóò ṣe àjọyọ̀ lórí Jérúsálẹ́mùn ó sì ní inú dídùn nínú àwọn ènìyàn mi;ariwo ẹkún àti igbeni a kì yóò gbọ́ nínú rẹ̀ mọ́,

20. “títí láé a kì yóò gbọ́ nínú rẹ̀ọmọ ọwọ́ tí yóò gbé fún ọjọ́ díẹ̀,tàbí àgbàlagbà tí kì yóò lo ọjọ́ ayé rẹ̀ tán;ẹni tí ó bá kú ní ìwọ̀n ọgọ́rùn-únni a ó pè ní ọ̀dọ́mọdé;ẹni tí kò ba le pé ọgọ́rùn-ún kanni a ó pè ní ẹni ìfibú.

21. Wọn yó kọ ilé, wọn yóò sì gbé nínú wọnwọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì jẹ èṣo wọn.

22. Wọn kì yóò kọ́ ilé fún ẹlòmìíràn láti gbé,tàbí kí wọn gbìn fún ẹlòmìíràn láti jẹ,Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí igi kan,bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí;àwọn àyànfẹ́ mi yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́wọn fún ìgbà pípẹ́.

23. Wọn kì yóò ṣe wàhálà lásántàbí kí wọn bímọ tí ọjọ́ iwájú wọnkì yóò sunwọ̀n;nítorí wọn yóò jẹ́ àwọn ènìyàn ti Olúwa bùkún fún,àwọn àti àwọn ìrandíran wọn pẹ̀lú wọn.

24. Kí wọn tó pè, èmi yóò dáhùn;nígbà tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, èmi yóò gbọ́.

25. Ìkookò àti ọ̀dọ́ àgùntàn yóò jẹun pọ̀,kìnìún yóò sì jẹ koríko gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù,ṣùgbọ́n erùpẹ̀ ni yóò jẹ́ oúnjẹ ejò.Wọn kì yóò panilára tàbí panirunní gbogbo òkè mímọ́ mi,”ni Olúwa wí.

Ka pipe ipin Àìsáyà 65