Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 63:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ta nì yìí tí ó ń bọ̀ láti Édómù,láti Bósírà, pẹ̀lú aṣọ rẹ̀ tí osùn ṣe àbàwọ́n fúnTa nì yìí, tí a wọ̀ ní aṣọ ẹ̀yẹ,tí ó ń yan bọ̀ wá nínú ọláńlá agbára rẹ̀?“Èmi ni bí, tí ó ń sọ̀rọ̀ nínú òdodotí ó nípa láti gbàlà.”

2. Èéṣe tí aṣọ yín fi pupagẹ́gẹ́ bí i tàwọn tí ń ṣiṣẹ́ ní ìfúntí?

3. “Èmi nìkan ti dá tẹ ìfúntí wáìnì;láti àwọn orílẹ̀ èdè tí ẹnikẹ́ni kò sì wà pẹ̀lú mi.Mo tẹ̀wọ́n mọ́lẹ̀ ní ìbínú mimo sì tẹ̀ wọ́n rẹ́ ní ìrunú miẹ̀jẹ̀ wọn sì fọ́n sí aṣọ mi,mo sì da àbàwọ́n sí gbogbo aṣọ mi.

4. Nítorí ọjọ́ ẹ̀san wà ní ọkàn miàti pé ọdún ìràpadà mi ti dé

5. Mo wò, ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan láti ṣe ìrànwọ́.Àyà fò mí pé ẹnikẹ́ni kò ṣèrànwọ́;nítorí náà apá mi ni ó ṣiṣẹ́ ìgbàlà fún miàti ìrunú mi ni ó gbémiró.

6. Mo tẹ orílẹ̀ èdè mọ́lẹ̀ nínú ìbínú mi;nínú ìrunú mi mo jẹ́ kí wọ́n mumo sì da ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀ lórí erùpẹ̀.”

Ka pipe ipin Àìsáyà 63