Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 60:14-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àwọn apọ́nilójú rẹ yóòwá foríbalẹ̀ fún ọ;gbogbo àwọn tí ó ti kẹ́gàn rẹ ni wọn yóò tẹríba níwájú rẹwọn yóò sì pè ọ́ ní Ìlú Olúwa,Ṣíhónì ti Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.

15. “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a ti kóríra rẹ, a sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀,láìsí ẹnìkan tí ó ń gba ọ̀dọ̀ rẹ kọjá,Èmi yóò ṣe ọ́ ní ìṣògo ayérayéàti ayọ̀ àtìrandíran.

16. Ìwọ yóò mu wàrà gbogbo orílẹ̀ èdèa ó sì rẹ̀ ọ́ ni ọmú àwọn ayaba.Nígbà náà ni ìwọ yóò mọ̀ pé Èmi Olúwa,èmi ni Olùgbàlà rẹ,Olùdáǹdè rẹ, Alágbára ti Jákọ́bù Nnì.

17. Dípò búróǹsì, èmi ó mú wúrà wá fún ọ,àti fàdákà dípò irun Dípò igi yóò mú búróńsì wá,àti irun dípò òkúta.Èmi yóò fi àlàáfíà ṣe gómínà rẹàti òdodo gẹ́gẹ́ bí alákòóso rẹ.

18. A kì yóò gbọ́ nípa rògbòdìyàn ní ilẹ̀ rẹ mọ́,tàbí ìdahoro àti ìparun nínú agbègbè rẹ,ṣùgbọ́n ìwọ yóò pe ògiri rẹ ní ìgbàlààti àwọn ẹnu bodè rẹ ní ìyìn.

19. Òòrùn kì yóò sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ní ọ̀sán mọ́,tàbí kí ìtànsán òṣùpá tún ràn sí ọ mọ́,nítorí Olúwa ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ayérayé,àti Ọlọ́run rẹ yóò jẹ́ ògo rẹ.

20. Òòrùn rẹ kì yóò sì wọ̀ mọ́,àti òṣùpá rẹ kì yóò sì wọ òòkùn mọ́; Olúwa ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ ayérayé rẹ,àti àwọn ọjọ́ arò rẹ yóò sì dópin.

21. Lẹ́yìn náà ni gbogbo àwọn ènìyàn rẹ yóò di òdodoàwọn ni yóò sì jogún ilẹ̀ náà títí ayé.Àwọn ni èhù tí mo ti gbìn,iṣẹ́ ọwọ́ mi,láti fi ọlá ńlá mi hàn.

22. Èyí tí ó kéré jù nínú un yín yóò di ẹgbẹ̀rún kan,èyí tí ó kéré yóò di orílẹ̀ èdè ńlá.Èmi ni Olúwa;ní àkókò rẹ̀ Èmi yóò ṣe èyí kánkán.”

Ka pipe ipin Àìsáyà 60