Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 60:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Dìde, tànmọ́lẹ̀, nítorí ìmọ́lẹ̀ rẹ ti dé,ògo Olúwa sì ràdọ̀bò ọ́.

2. Kíyèsí i, òkùnkùn bo ilẹ̀ ayéòkùnkùn biribiri sì wà lórí àwọn ènìyàn,ṣùgbọ́n Olúwa ràn bò ọ́ògo rẹ̀ sì farahàn lóríi rẹ.

3. Àwọn orílẹ̀ èdè yóò wá sí ìmọ́lẹ̀ rẹ,àti àwọn ọba sí ìmọ́lẹ̀ òwúrọ̀ rẹ.

4. “Gbé ojú rẹ ṣókè kí o sì wò yíká rẹ:Gbogbo wọn gbárajọ wọ́n sì wá sọ́dọ̀ rẹ;àwọn ọmọ rẹ wá láti ọ̀nà jíjìn,àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrìn rẹ ni a gbé ní apá.

Ka pipe ipin Àìsáyà 60