Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 58:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Kígbe rẹ̀ ṣókè, má ṣe fà ṣẹ́yìn.Gbé ohùn rẹ ṣókè bí i ti fèrè.Jẹ́ kí ó di mímọ̀ fún áwọn ènìyàn mi, ọ̀tẹ̀ wọnàti fún ilé Jákọ́bù ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

2. Nítorí ọjọ́ dé ọjọ́ ni wọ́n ń wá mi kiri;wọ́n ṣe bí ẹni ní ìtara láti mọ ọ̀nà mi,àfi bí ẹni pé wọ́n jẹ́ orílẹ̀ èdè kan tí ń ṣe ohun tí ó tọ̀nàtí òun kò sì tí ì kọ àṣẹ Ọlọ́run rẹ̀.Wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ mi fún ìpinnu nìkanwọ́n sì ṣe bí ẹni ń tara fún Ọlọ́run láti súnmọ́ ọ̀dọ̀ wọn.

3. ‘Èéṣe tí àwa fi ń gbààwẹ̀,’ ni wọ́n wí,‘tí ìwọ kò sì tí ì rí?Èéṣe tí àwa fi rẹra wa sílẹ̀,tí ìwọ kò sì tí ì ṣe àkíyèsí?’“Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ ní ọjọ́ ààwẹ̀ yín, ẹ̀yin ń ṣe bí ó ti wù yínẹ sì ń pọ́n àwọn òṣìṣẹ́ yín gbogbo lójú.

4. Ààwẹ̀ yín sì parí nínú ìjà àti asọ̀,àti lílu ọmọnìkejì ẹni pẹ̀lú ẹṣẹ́ ìkà.Ẹ̀yin kò le è gbààwẹ̀ bí ẹ ti ń ṣe lónìíkí ẹ sì retí kí a gbọ́ ohùn un yín ní ibi gíga.

5. Ǹjẹ́ èyí ha ni irú ààwẹ̀ tí mo yàn bí,ọjọ́ kanṣoṣo fún ènìyàn láti rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀?Í haá ṣe kí ènìyàn tẹ orí i rẹ̀ ba bí i koríko láṣán ni bíàti ṣíṣùn nínú aṣọ ọ̀fọ̀ àti eérú?Ṣé ohun tí ẹ̀ ń pè ní ààwẹ̀ nìyí,ọjọ́ ìtẹ́wọ́gbà fún Olúwa?

Ka pipe ipin Àìsáyà 58