Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 55:6-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ẹ wá Olúwa nígbà tí ẹ lè rí i;ẹ pè é nígbà tí ó wà nítòsí.

7. Jẹ́ kí ìkà kí ó kọ ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀àti ènìyàn búburú èrò rẹ̀.Jẹ́ kí ó yípadà sí Olúwa, Òun yóò sì ṣàánú fún un,àti sí Ọlọ́run wa, nítorí Òun yóò sì dáríjìn ín jọjọ.

8. “Nítorí èrò mi kì í ṣe èrò yín,tàbí ọ̀nà yín a há máa ṣe ọ̀nà mi,?”ni Olúwa wí.

9. “Gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti ga ju ayé lọ,bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín lọàti èrò mi ju èrò yín lọ.

10. Gẹ́gẹ́ bí òjò àti sílóòti wálẹ̀ láti ọ̀runtí kì í sì padà sí ibẹ̀láì bomirin ilẹ̀kí ó sì mú kí ó tanná kí ó sì rudi,tó bẹ́ẹ̀ tí yóò fi mú irúgbìn fún afúnrúgbìnàti àkàrà fún ọ̀jẹun,

11. bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ mi tí ó jáde láti ẹnu mi wá;kì yóò padà sọ́dọ̀ mi lọ́wọ́ òfo,ṣùgbọ́n yóò ṣe ohun tí mo fẹ́,yóò sì mú ète mi tí mo fi rán an wá sí ìmúṣẹ.

12. Ẹ̀yin yóò jáde lọ ní ayọ̀a ó sì daríi yín lọ ní àlàáfíà;òkè ńlá ńlá àti kéékèèkééyóò bú sí orin níwájúu yínàti gbogbo igi inú un pápáyóò máa pàtẹ́wọ́.

13. Dípò igi ẹ̀gún ni igi páìnì yóò máa dàgbà,àti dípò ẹ̀wọ̀n, mítílì ni yóò yọ.Èyí yóò wà fún òkìkí Olúwa,fún àmì ayérayé,tí a kì yóò lè parun.”

Ka pipe ipin Àìsáyà 55