Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 55:3-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Tẹ́tí sílẹ̀ kí o sì wá sọ́dọ̀ migbọ́ tèmi, kí ọkàn rẹ lè wà láàyè.Èmi yóò dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lúù rẹ,ìfẹ́ Òtítọ́ tí mo ṣèlérí fún Dáfídì.

4. Kíyèsí i, mo ti fi òun ṣe ẹlẹ́rìí fún àwọn ènìyàn,olórí àti apàṣẹ fún àwọn ènìyàn.

5. Lótìítọ́ ìwọ yóò ké sí àwọn orílẹ̀ èdè tí ìwọ kò mọ̀àti orílẹ̀ èdè tí ìwọ kò mọ̀ ni yóò sáré tọ̀ ọ́ wá,Nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹẸni Mímọ́ Ísírẹ́lìnítorí pé ó ti fi ohun dídára dá ọ lọ́lá.”

6. Ẹ wá Olúwa nígbà tí ẹ lè rí i;ẹ pè é nígbà tí ó wà nítòsí.

7. Jẹ́ kí ìkà kí ó kọ ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀àti ènìyàn búburú èrò rẹ̀.Jẹ́ kí ó yípadà sí Olúwa, Òun yóò sì ṣàánú fún un,àti sí Ọlọ́run wa, nítorí Òun yóò sì dáríjìn ín jọjọ.

8. “Nítorí èrò mi kì í ṣe èrò yín,tàbí ọ̀nà yín a há máa ṣe ọ̀nà mi,?”ni Olúwa wí.

9. “Gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti ga ju ayé lọ,bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín lọàti èrò mi ju èrò yín lọ.

Ka pipe ipin Àìsáyà 55