Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 55:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Ẹ wá, gbogbo ẹ̀yin tí òrùngbẹ ń gbẹ,ẹ wá sí ibi omi;àti ẹ̀yin tí kò ní owó;ẹ wá, ẹ rà kí ẹ sì jẹ!Ẹ wá ra wáìnì àti mílíìkìláìsí owó àti láìdíyelé.

2. Èéṣe tí ẹ fi ń ná owó fún èyí tí kì í ṣe àkàrààti làálàá yín lórí ohun tí kì í tẹ́nilọ́rùn?Tẹ́tísílẹ̀, tẹ́tí sí mi, kí ẹ sì jẹ èyí tí ó dára,bẹ́ẹ̀ ni ọkàn yín yóò láyọ̀ nínú ọrọ̀ tí ó bójúmu.

3. Tẹ́tí sílẹ̀ kí o sì wá sọ́dọ̀ migbọ́ tèmi, kí ọkàn rẹ lè wà láàyè.Èmi yóò dá májẹ̀mú ayérayé pẹ̀lúù rẹ,ìfẹ́ Òtítọ́ tí mo ṣèlérí fún Dáfídì.

4. Kíyèsí i, mo ti fi òun ṣe ẹlẹ́rìí fún àwọn ènìyàn,olórí àti apàṣẹ fún àwọn ènìyàn.

5. Lótìítọ́ ìwọ yóò ké sí àwọn orílẹ̀ èdè tí ìwọ kò mọ̀àti orílẹ̀ èdè tí ìwọ kò mọ̀ ni yóò sáré tọ̀ ọ́ wá,Nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹẸni Mímọ́ Ísírẹ́lìnítorí pé ó ti fi ohun dídára dá ọ lọ́lá.”

6. Ẹ wá Olúwa nígbà tí ẹ lè rí i;ẹ pè é nígbà tí ó wà nítòsí.

7. Jẹ́ kí ìkà kí ó kọ ọ̀nà rẹ̀ sílẹ̀àti ènìyàn búburú èrò rẹ̀.Jẹ́ kí ó yípadà sí Olúwa, Òun yóò sì ṣàánú fún un,àti sí Ọlọ́run wa, nítorí Òun yóò sì dáríjìn ín jọjọ.

8. “Nítorí èrò mi kì í ṣe èrò yín,tàbí ọ̀nà yín a há máa ṣe ọ̀nà mi,?”ni Olúwa wí.

Ka pipe ipin Àìsáyà 55