Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 54:7-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. “Fún ìgbà díẹ̀ ni mo kọ̀ ọ́ sílẹ̀,ṣùgbọ́n pẹ̀lú ọkàn ìyọ́nú èmi yóòmú ọ padà wá.

8. Ní ríru ìbínú.Mo fi ojú pamọ́ fún ọ fún ìṣẹ́jú kan,ṣùgbọ́n pẹ̀lú àánú àìnípẹ̀kunÈmi yóò síjú àánú wò ọ́,”ni Olúwa Olùdáǹdè rẹ wí.

9. “Sí mi, èyí dàbí i àwọn ọjọ́ Núà,nígbà tí mo búra pé àwọn omiNúà kì yóò tún bo ilẹ̀ ayé mọ́.Bẹ́ẹ̀ ni nísinsìnyìí mo ti búra láti má ṣe bínú sí ọ,bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò bá ọ wí mọ́.

10. Bí a tilẹ̀ mi àwọn òkè ńlátí a sì sí àwọn òkè kékeré nídìí,Ṣíbẹ̀ ṣíbẹ̀ ìfẹ́ àìkùnà mi fún ọ kì yóò yẹ̀ láéláétàbí májẹ̀mú àlàáfíà ni a ó mú kúrò,”ni Olúwa, ẹni tí ó síjú àánú wò ọ́ wí.

11. Ìwọ ìlú tí a pọ́n lójú, tí ìjì ń gbá kirití a kò sì tù nínú,Èmi yóò fi òkúta tìróò kọ́ ọàti ìpìlẹ̀ rẹ pẹ̀lú sáfírésì.

12. Èmi yóò fi rúbísì ṣe odiì rẹ,àwọn ẹnu ọ̀nà ni a ó fi ohun èlò dáradára fún,àti àwọn ògiri rẹ pẹ̀lú òkúta iyebíye.

13. Gbogbo ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ ni Olúwa yóò kọ́,àlàáfíà àwọn ọmọ rẹ yóò jẹ́ ńlá àti púpọ̀.

14. Ní òdodo ni a ó fi ìdí rẹ kalẹ̀Ìwà ipá yóò jìnnà sí ọo kò ní bẹ̀rù ohunkóhunÌpayà la ó mú kúrò pátapáta;kò ní súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ.

15. Bí ẹnikẹ́ni bá tilẹ̀ bá ọ jà, kò ní jẹ́ láti ọwọ́ọ̀ mi;ẹnikẹ́ni tí ó bá bá ọ jà ni yóò túúbá fún ọ.

16. “Kíyèsí i, Èmi ni ó dá alágbẹ̀dẹtí ń fẹ́ iná èédú di èjò-inátí ó sì ń mú ohun èlò wá tí ó bá iṣẹ́ rẹ mu.Èmi náà sì ni ẹni tí ó dá apanirun láti ṣe iṣẹ́ ibi;

17. Kò sí ohun ìjà tí a ṣe sí ọ tí yóò ṣe nǹkan,ìwọ yóò já ahọ́nkáhọ́n tó bá fẹ̀ṣùn kàn ọ́ kulẹ̀.Èyí ni ogún àwọn ìránṣẹ́ Olúwa,èyí sì ni ìdáláre wọn láti ọ̀dọ̀ mi,”ni Olúwa wí.

Ka pipe ipin Àìsáyà 54