Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 54:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Kọrin, Ìwọ obìnrin àgàn,ìwọ tí kò tí ì bímọ rí;búsí orin, ẹ hó fún ayọ̀,ẹ̀yin tí kò tí ì rọbí rí;nítorí pé púpọ̀ ni ọmọ àwọn obìnrin ìsọdahoroju ti ẹni tí ó ní ọkọ,”ni Olúwa wí.

2. Fẹ ibi àgọ́ rẹ lójú sí i,fẹ aṣọ àgọ́ rẹ kí ó gbòòrò sí i,má ṣe dá a dúró;sọ okùn rẹ di gígùn,mú òpo rẹ lágbára sí i.

3. Nítorí ìwọ ó fẹ̀ sọ́tùn-ún àti sí òsì;ìrandíran rẹ yóò jogún àwọn orílẹ̀ èdè,wọn yóò sì dó sí ahoro àwọn ìlú wọn.

Ka pipe ipin Àìsáyà 54