Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 52:3-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa wí;“Ọ̀fẹ́ ni a tà ọ́,láìsanwó ni a ó sì rà ọ́ padà.”

4. Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.“Ní ìgbà àkọ́kọ́ àwọn ènìyàn mi ṣọ̀kalẹ̀lọ sí Éjíbítì láti gbé;láìpẹ́ ni Áṣíríà pọ́n wọn lójú.

5. “Àti ní àkókò yìí, kí ni mo ní níbí?” ni Olúwa wí.“Nítorí a ti kó àwọn ènìyàn mi lọ lọ́fẹ̀ẹ́,àwọn tí ó sì ń jọba lé wọn fi wọ́n ṣẹlẹ́yà,”ni Olúwa wí.“Àti ní ọjọọjọ́orúkọ mi ni a ṣọ̀rọ̀ òdì sí nígbà gbogbo.

6. Nítorí náà àwọn ènìyàn mi yóò mọ orúkọ mi;nítorí ní ọjọ́ náà, wọn yóò mọ̀pé Èmi ni ó ti sọ àṣọtẹ́lẹ̀ rẹ̀.Bẹ́ẹ̀ ni, Èmi ni.”

7. Báwo ni ó ṣe dára tó lórí òkèẹṣẹ̀ àwọn tí ó mú ìyìn rere ayọ̀ wá,tí wọ́n kéde àlàáfíà,tí ó mú ìyìn rere wá,tí ó kéde ìgbàlà,tí ó sọ fún Ṣíhónì pé,“Ọlọ́run rẹ ń jọba!”

8. Tẹ́tísílẹ̀! Àwọn olùṣọ́ rẹ gbé ohùn wọn ṣókèwọ́n kígbe papọ̀ fún ayọ̀.Nígbà tí Olúwa padà sí Ṣíhónì,wọn yóò rí i pẹ̀lú ojúu wọn.

Ka pipe ipin Àìsáyà 52