Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 52:10-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Olúwa yóò sí apá mímọ́ rẹ̀ sílẹ̀ní ojú gbogbo orílẹ̀ èdè,àti gbogbo òpin ilẹ̀ ayé yóò ríìgbàlà Ọlọ́run wa.

11. Ẹ túká, ẹ túká, ẹ jáde kúrò níhìnínyìí!Ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kan!Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀ kí ẹ sì di mímọ́,ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé ohun èlò Olúwa.

12. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò yára kúròtàbí kí ẹ ṣáré lọ;nítorí Olúwa ni yóò ṣíwájúu yín lọ,Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni yóò sì ṣe ààbò lẹ́yìn ín yín.

13. Kíyèsí i, ìránṣẹ́ mi yóò hùwà ọlọgbọ́n;òun ni a ó gbé ṣókè tí a ó sì gbégaa ó sì gbé e lékè gidigidi.

14. Gẹ́gẹ́ bí a ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n ń bọlá fún un—ìwò ojú rẹ ni a ti bà jẹ́ kọjá ti ẹnìkẹ́ni àti ìrísí rẹ̀ ní a ti bàjẹ́ kọjá ohun tí ènìyàn ń fẹ́

15. bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe bomirin àwọn orílẹ̀ èdè ká,àwọn ọba yóò sì pa ẹnu wọn mọ́ nítoríi rẹ̀.Nítorí ohun tí a kò sọ fún wọn, wọn yóò rí i,àti ohun tí wọn kò tí ì gbọ́, ni yóò sì yé wọn.

Ka pipe ipin Àìsáyà 52