Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 50:8-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Ẹni tí ó dámiláre wà nítòsí.Ta ni ẹni náà tí yóò fẹ̀ṣùn kàn mí?Jẹ́ kí a kojú ara wa!Ta ni olùfisùn mi?Jẹ́ kí ó kòmí lójú!

9. Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó ń ràn mí lọ́wọ́.Ta ni ẹni náà tí yóò dámí lẹ́bi?Gbogbo wọn yóò gbó bí aṣọ;kòkòrò ni yóò sì mú wọn jẹ.

10. Ta ni nínú yín tí ó bẹ̀rù Olúwatí ó sì ń gbọ́ràn sí ìràńṣẹ́ rẹ̀ lẹ́nu?Jẹ́ kí ẹni tí ń rìn ní òkùnkùntí kò ní ìmọ́lẹ̀,kí ó gbẹ́kẹ̀lé orúkọ Olúwakí o sì gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run rẹ̀.

11. Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí, gbogbo ẹ̀yin ti ń tannátí ẹ sì ń pèṣè iná ìléwọ́ fún ara yín,ẹ lọ, kí ẹ sì máa rìn nínú ìmọ́lẹ̀ iná yínàti ti ìtùfú tí ẹ ti kánná lù.Ohun tí ẹ ó gbà lọ́wọ́ mi nìyìí:Ẹ̀yin ó dùbúlẹ̀ nínú ìpọ́njú.

Ka pipe ipin Àìsáyà 50