Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Àìsáyà 50:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ohun tí Olúwa wí níyìí:“Níbo ni ìwé-ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ìyá rẹ wàèyí tí mo fi lé e lọ?Tàbí èwo nínú àwọn olùyánilówó mini mo tà ọ́ fún?Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ ni a fi tà ọ́;nítorí àìṣedéédéé rẹ ni a fi lé ìyá rẹ lọ.

2. Nígbà tí mo wá, èéṣe tí a kò fi rí ẹnìkan?Nígbà tí mo pè, èéṣe tí kò fi sí ẹnìkan láti dáhùn?Ọwọ́ mi a kúrú láti gbà ọ́?Èmi kò ha ní agbára láti gbà ọ́ bí?Nípa ìbáwí lásán, Èmi gbẹ omi òkun,Èmi yí àwọn odò sí aṣálẹ̀;àwọn ẹja wọn rà fún àìsí omiwọ́n sì kú fún òùngbẹ.

3. Èmi fi òkùnkùn bo sánmọ̀mo sì fi aṣọ-ọ̀fọ̀ ṣe ìbòrí rẹ̀.”

4. Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti fún mi ni ahọ́n tí a fi iṣẹ́ rán,láti mọ àwọn ọ̀rọ̀ tí ó lè gbé àwọn aláàárẹ̀ ró.O jí mi láràárọ̀,o jí etí mi láti gbọ́ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí à ń kọ́.

5. Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti sí mi ní etí,bẹ́ẹ̀ ni èmi kò ṣọ̀tẹ̀ rí;Èmi kò sì padà ṣẹ́yìn.

Ka pipe ipin Àìsáyà 50